Ìjọba DéÀpẹrẹ
ÀDÚRÀ:
Ọlọ́run, fún mí ní ojú láti bojú wo àgbáyé bí ó tí ṣe rí sí àti láti rí àwọn ènìyàn miran bí ó tí ṣe rí wọn pẹ̀lú.
Ẹ̀KỌ́ KÍKÀ :
Tí ó bá jẹ òbí, tàbí, ní àkókò tí ó wà ní ọmọdé, ó tí ní ìrírí bí a tì ń ṣe wàrà tí sokolétì. Nítorí náà o mọ pe nígbàtí ó bá bẹ̀rẹ̀ si rírò wàrà náà tí ó sì pá àwọ̀ dá tí ó kúrò ní funfun sì àwọ̀ súẹ́ súẹ́, kí ìṣe ète idán rárá. Ọ̀ jẹ́ nítorípé sokoleti olómi tí wá ní ìsàlẹ̀ gíláàsì ni. Gbogbo èròjà tí a nílò láti pá àwọ̀ wàrà náà dá sí sokoleti tí wá níbẹ̀, ṣùgbọ́n a ní láti ro papọ̀ láti mú àyípadà wá.
Oǹkọ̀wé ìwé Hébérù ń sọ wípé ìbárajọ kan wà ní ìgbé ayé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. A ní àfiyèsí ẹ̀bùn àti agbára fún "ìfẹ́ àti iṣẹ́ rere" tí ó tóbi nínú wa. Ṣùgbọ́n ní ìgbà míràn àwọn ẹ̀bùn àfiyèsí yí tí lè pirọrọ. Yíò tí wá ní ìsàlẹ̀ pátápátá tó bẹ̀ẹ́ tí kò ní rí àyè láti jí sókè láti ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ kí ó ṣe nínú ayé níbi tí a ti nílò rẹ.
Eléyì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn pàtàkì julọ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lè fún ara wọn. Nwọn lè jẹ oníjọ̀ngbọ̀n, tí wọn kò fẹ́ kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ayé wá. Nwọn si le ba ara wọn ṣiṣẹ́ pọ kí wọn sì rú ìfẹ́ sókè nípa ìwúrí, ìṣirò àti àtìlẹ́hìn tí ó péye.
A ní láti yan irú àwọn ìbásepọ̀ bayi ni àyò ni ìgbé ayé wa. A sì tún ní láti gbà àwọn míràn láyè láti bá wà sọ òdodo ọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó korò létí wá-tàbí ó fá ìrunú. Nígbà gbogbo ní a rí wí pé ìpọ́njú díẹ̀ ni a nílò láti ṣe àwárí ìfẹ́ àti ìdí tí a fi wá s'aye tí ó gá julọ.
ÌJÍRÒRÒ:
Yíyàn àwọn ìbásepọ̀ tí ó ní ìlera pípé l'áàyo ni ó ń mú wá tẹ̀ síwájú ó sì mú ìmọ́ọ̀mọ̀se àti àìlágbárá dání. Nípa àdúrà ṣe àkíyèsí àwọn tí ó yí ọ ká - bí ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn alábásísẹ́pọ́ rẹ. Àwọn díẹ̀ wo ni ó ní ìgbàlà julọ? O sese kí ó jẹ wípé àwọn tí ó ní ìgbàlà julọ kò sún mọ́ ọ rárá, ṣùgbọ́n ìwọ yíò fẹ́ láti sún mọ́ wọn nítorí pé wọ́n dára sì ọ. Kíni yíò tí rí fún ọ ti o ba gbà àwọn tí ó ní ìgbàlà yí láyè láti bá ọ sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ ni ọna ti o rinlẹ? Ro pípè wọn láti bá ọ rìn pẹ́kípẹ́kí àti láti mọ ọ díẹ̀ sì ni ìdánilójú, ìdọ̀tí àti gbogbo rẹ.
Béèrè lọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ láti ṣe àfihàn àwọn ènìyàn tí Ó fẹ fà sínú ayé rẹ láti bá ọ síṣẹ́ pọ. Lẹhin náà tọ wọn lọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.
More