Dídaríji àwọn tó páwa láraÀpẹrẹ
Ẹwà tó wà nínú Ìdáríjì
Ìdáríjì gẹ́gẹ́ bíi ìlànà Bíbélì dá lórí ọgbé forgiveness deals directly and specifically with personal injuries, bó ti wù kí ó jìn tó tàbí ki o pẹ tó láti ẹ̀yìn wá. Ìgbàkúùgbà tí a bá ń gbé àwọn àṣìṣe àtẹ̀yìnwá wò, ó ṣe pàtàkì láti pe àwọn ẹ̀sẹ̀ yìí ní orúkọ wọn pàtó. Tí a bá ṣe eléyìí, à ún ṣe ìdá mọ̀ oun tí ó jẹ́ wàhálà gan-an, a sì ń jẹ́wọ́ rẹ̀. Nínú Ìwé Mímọ́, kí "á jẹ́wọ́" túmọ̀sí kí á "gbà" pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ bá tí rí. Tí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ wa bí ó ṣe jẹ́, à ún gbà pẹ̀lú Ọlọ́run ní tòótọ́ bí irú wàhálà tí ó wà láàrin wa àti àwọn ẹlòmíràn.
Jákọ́bù fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn tó ọlọ́gbọ́n; ó sọ fún wọn pàtó oun tí wọ́n nílò láti sọ: “Jọ̀wọ́ dárí jì àwọn arákùnrin rẹ fún àṣìṣe ńlá tí wọ́n ṣe sí ọ—fún ẹ̀sẹ̀ wọn láti ṣe ọ́ níbi.” Gbólóhùn yi “àṣìṣe ńlá” tún lè túmọ̀sí “ibi.” Ní àkókò ìjẹ́wọ́ a lè fẹ́ fi ẹnu bu ẹ̀sẹ̀ wá tàbí ti àwọn ẹlòmíràn kéré. Ìhùwàsí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù síi kò fi ohunkóhun yàtọ̀ sí ibi. Jósẹ́fù mọ̀ dájú bí ìbàjẹ́ ọkàn wọn ti jinlẹ̀ tó. Èyí ni àjàgà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ń rù kiri fún ọdún pipẹ́, ẹrú ẹ̀bi tí ó mú wọn bẹ̀rù Jósẹ́fù—ósì lẹtọ bẹ́ẹ̀! Wọ́n jẹ̀bi ibi ṣíṣe sí ẹnití ó wà ní wájú wọn báyìí gẹ́gẹ́ bí oní ìdájọ́. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ́wọ́ ìwà ibi wọn, ǹjẹ́ Jósẹ́fù hùwà sí wọn padà nípa fífi ibi kún ibi won? Rárá o! Jósẹ́fù sun ẹkùn! Ó ríi pé ìfẹ́ Ọlọ́run náà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú ìwà ibi àwọn arákùnrin rẹ̀. Fún ìdí èyí ó leè dárí ji àwọn arákùnrin rẹ̀ ó sì tù wọ́n nínú, ó sì lè mú kí àjọṣepọ̀ tó yẹ lè padà bọ̀ sípò.
Jòhánù 1 orí 1: ẹsẹ̀ 9 sọ pé, “Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo.” Wo ẹwà ìdáríjì! Ìdáríjì lè lọ tààrà padà sí àṣìṣe ọlọ́jọ pipẹ́ sẹ́yìn, a sì máa tú ní sílẹ̀ kúrò lábẹ́ àjàgà àti ìgbà èwe wá.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bóyá a nje ìrora ojú ogbé okàn tàbí tí ara, ìdaríji ní ìpìlê ìgbé ayé Kristẹni. Jésù Kristi nírírí onírúurú ohun tí kò tọ̀nà àti hùwàsí ti kódà títí dé ikú àìtó. Síbè ní wákàtí tó kéyìn, o daríji olè tó ṣe yèyé é lórí àgbélèbú àti bákan náà àwọn múdàájọ́ṣẹ e.
More