Dídaríji àwọn tó páwa láraÀpẹrẹ
Mímú Ìbáṣepọ̀ Padà Bọ̀sípò
Ṣé o máá nronú lórí àwọn ìbáṣepọ̀ kan nítorípé wọ́n mẹ́hẹ tí wọ́n sì kún fún ìbànújẹ́?
Ó maá ńṣòro láti ní ayọ̀ ọkàn nígbàtí ọkàn ènìyàn bá pòrúúru. Àwọn ìkùnsínú kan lè wà láàrin àwa àti àwọn ẹlòmíràn tí o lè pa'gi dí'nà ìbáṣepọ̀ wa pẹlú Ọlọrun Mímọ́. Ìjọsìn wa gbọdọ̀ mọ́ kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù. Ìdáríjì tí a rí gbà nínú Jésù fún wà ní ààyè tààrà sōdọ̀ Ọlọ́run, sùgbọ́n Ó pòǹgbẹ pé kí a dàbí Ọmọ Òun. Jésù rọ̀ wá láti “ṣe ìlàjà” láàrin àwa àti àwọn ẹlòmíràn. Láti ṣe ìlàjà ni láti dá ìbáṣepọ̀ padà sí èyí tí o dúró déédéé. À ń bu Krístì kù nígbàtí àwọn ìbáṣepọ̀ wa kò bá ní láárí. Nípa dídáríjini a lè mú àwọn ìbáṣepọ̀ wa padà bọ̀ s'ípò kí a sì wá s'ọ́dọ̀ Ọlọ́run nínú ìjọsìn pẹlú ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́. Bíotìlẹ̀jẹ́pé ẹnìkejì lè má fẹ́ láti bá wa l'àjà, a kàn n'ípá fún wa láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti bá wọn l'àjà.
Bí a bá ńgbé irú ìgbé ayé báyìí, à ń bu ọlá fún Krístì, ìjọsìn wa sí Ọlọ́run sì já gaara. Bí a ṣé ńdàgbà tí a sì ń dàbíi Krístì, a ó ríi wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkùnsínú ni a lè "f'ojú fò dá.” A ó yàn láti má bínú (ṣe àyẹ̀wò Òwe 19:11). A ó dáríji àwọn ẹlòmíràn, nítorípé a mọ̀ pé àwa àti àwọn ẹlòmíràn a máa ṣe ara wa láìmọ̀. Ìdáhùn tó kún fún oore-ọ̀fẹ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ́ṣẹ̀ ni eléyìí, èyí tí yíò mú ìtahùn sí ara ẹni kúrò tí kò sì níí jẹ́ kí ìbàṣepọ̀ bàjẹ́. Irú ìwà àgbà báyìí tú wa sílẹ̀ láti gbádùn ìbájọ́sìn aláìní ìdíwọ́ pẹ̀lú Ọlọrun àti pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bóyá a nje ìrora ojú ogbé okàn tàbí tí ara, ìdaríji ní ìpìlê ìgbé ayé Kristẹni. Jésù Kristi nírírí onírúurú ohun tí kò tọ̀nà àti hùwàsí ti kódà títí dé ikú àìtó. Síbè ní wákàtí tó kéyìn, o daríji olè tó ṣe yèyé é lórí àgbélèbú àti bákan náà àwọn múdàájọ́ṣẹ e.
More