Gbígbé Nípa Ti Ẹ̀mí Mímọ́: Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì Pẹ̀lú John PiperÀpẹrẹ
Ẹ̀mí Mímọ́ Fún Wa Ní Ìdààbò Bò
Nínú Rẹ̀ ni...a ti dì wá ni...èdìdí pẹ̀lú ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnì tó jé ìdánilójú ohun ìní wa títí ti a óò fi gba a, sí ilé ògo Rẹ̀. —Éfésù 1:13-14
Ìfẹ́ Ọlọ́run ńlá fún àwọn ènìyàn Rè ní pe kí wọn ní ìmọ̀lára ààbò nínú ìfẹ́ àti agbára Rè. Gbogbo ohun yòókù lè máa se déédéé —ìlera wa, ìdílé wa, isé wa, ẹ̀kọ́ wa, àwùjọ wa, ayé tán gbé. Ní èyíkéyìí ìpele yìí o lè ní ìmọ̀lára pé o wà lórí ihò alájà ogójì lókè nínú afẹ́fẹ́ àìlèse pàtó. O ní ìmọ̀lára pé o kò dúró déédéé àti pé o ń subú, àti gbogbo bíríkì tí o mú yo kúrò nínú àpò sìmẹ́ǹtì rè.
Níwọ̀n bí Ọlọ́run se gbogbo nǹkan fún ìyìn ògo Rè, àti pé níwọ̀n bí gbigbàgbó nínú ọ̀rọ̀ náà gbé ògo Rè ga náà, Ọlọ́run gbé ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání láti gba fún Ara rè ìgbé-ga ògo Rè títí ayé: o se èdìdì onígbàgbó náà pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, àti fún ìdánilójú pé a máa wà sínú ohun ìní wa pẹ̀lú yìnyín ògo Rè.
Ọlọ́run ìtara ìfara-enìji láti ni àwọn ènìyàn fún ohun ìní Rè tó ń gbé fún ìyìn ògo Rè títí láé ti Kò ṣe tàn láti jé kí ayànmo àìnípẹ̀kun wa gbára lé agbára ìbílẹ̀ láti se ìfẹ́ ọkàn tàbí síse. Ó pàṣẹ Èmí Mímọ́ Rè sínú ayé wa láti dààbò bò wa títí ayé.
Ọlọ́run ràn Ẹ̀mí Mímọ́ Rè bí èdìdì ìpámọ́ láti de ìgbàgbọ́ wa, gẹ́gẹ́ bí ojúlówó èdìdì láti jé kí ipò jíjẹ ọmọ wa lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí èdìdì tó ń dáàbò bò láti má jẹ kí àwọn ipá tí ń pani rún ráàyè wọlé. Kókó ní pé Ọlọ́run fẹ́ jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ àti wà ní ààbò nínú ìfẹ́ àti agbára Rè.
Ní Éfésù 1:14, Ọlọ́run ń sọ wípé, “Ìfẹ́ ọkàn Mi ńlá fún àwọn tó gbàgbó nínú mi ni pé ọkàn yín yóò balẹ̀ nínú ìfẹ́. Èmi ti yàn yin kí ìpìlè ayé to wà. Mo fún o ni àyànmọ́ láti jé àwọn omo mi títí ayé. Mo tí rà yín padà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Ọmọ mi. Àti pé mo ti fi Ẹ̀mí Mi sínú yín gẹ́gẹ́ bí èdìdì àti ìdánilójú. Torí náà, e máa gba ohun ìní yín àti yìn ògo oore-òfé mi láyé àti láé.
Àtipe mo sọ fún o ní Éfésù 1 nítorí Mo fẹ́ kí ọkàn rè balẹ̀ nínú ìfẹ́ àti agbára Mi. Mi kò ṣèlérí ìgbé ayé tó rọrùn fún e. Kódà, nípasẹ̀ òpò ìpọ́njú o gbọ́dọ̀ wọnú ìjoba (Isé Àpọ́sítélì 14:22). Jẹ́ kín so lè kan sí: Mo ti yàn e. Mo ti fún o ni kádàrá; Mo ti rà o padà;Mo ti de e ní èdìdì nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Mi. Ohun rè ìní dájú, nítorí Mo ni ìtara ìfara-enìji láti gbé ògo oore-òfé Mi ga nínú ìgbàlà rè.”
Kọ́ ẹ̀kọ́ síi: http://www.desiringgod.org/messages/sealed-by-the-spirit-to-the-day-of-redemption
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èkọ́ Àṣàrò Bíbélì Méje látọwọ́ John Piper nípa Ẹ̀mí Mímọ́
More