Àwọn Ìkùnà Wa Gẹ́gẹ́ bí KristẹniÀpẹrẹ
Kókó
Gbogbo ìwé Ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni ó sọ ìtàn ìkùnà ńlá ti Peteru pẹ̀lú ìsọníṣókí tí Matiu fi sọ ìtàn náà.
Ìkùnà Peteru nínú àyọkà yìí yé mi nítorí pé n kò lè sọ pé ńṣe ni èmi ìbá dúró wámú nígbà tí Peteru kò lè dúró.
A ms láti inú àwọn ìtàn ìhìnrere, ní nǹkan bí wákàtí méjì ṣáájú, Peteru ti gbìyànjú láti dènà mímú Kristi nínú Ọgbà Gẹsimaani nípasẹ̀ fífi idà gé etí ẹrú olórí àlùfáà. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀, nínú àyọkà yìí, Peteru domi fún ẹ̀rù níwájú ìránṣẹ́bìnrin nínú àgbàlá olórí àlùfáà.
Peteru, ọkùnrin tí ó kún fún ìyànjú àti èrò rere ní bí i wákàtí méjì sẹ́yìn, wá kún fún ìtìjú, ìbànújẹ́, ẹ̀rù àti omíjé. Peteru, ọkùnrin tí ó búra pé òun yóò kú fún Jesu, wá ń búra jákè lẹ́ẹ̀mẹta pé òun kò tilẹ̀ mọ Jesu. Ní kúkúrú, Peteru kùnà, ó sì kùnà náà gidi
Ṣùgbọ́n ìtàn ìkùnà Peteru kò dá yàtọ̀ nínú Bíbélì. Gbogbo Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin kún fún ìtàn kókó ìkùnà ènìyàn.
Adamu àti Eefa kùnà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé nínú ayé tí ó pé. Abrahamu kùnà; ó pa irọ́ nípa ìyàwó rẹ̀. Mose, ọkùnrin tí Ọlọ́run lò láti gba àwọn ọmọ Israeli là kúrò ní Ejibiti, kùnà láti wọ ilẹ̀ ìlérí.
Dafidi, ọkùnrin ẹni bí ọkàn Ọlọ́run, kùnà gidi gan-an: ó ṣe panságà pẹ̀lú Bathseba ó sì pa ọkọ̀ rẹ̀. Solomọni, ọmọ Dafidi, kùnà nípasẹ̀ mímú ìbọ̀rìṣà wọ Israẹli lẹ́ẹ̀kan sí i. ní gbogbo Májẹ̀mú láéláé, àwọn ènìyàn Ọlọ́run kùnà láti ìran dé ìran nípasẹ̀ ìbọ̀rìṣà léraléra tí wọ́n gùn lé àti àìgbọràn sí Ọlọ́run.
Májẹ̀mú Titun náà sọ ìtàn ìkùnà àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Kódà nínú ìtàn ìkùnà Peteru yìí, Matiu sọ fún wa pé gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ló gúra pé àwọn kò ní ṣẹ́ Jesu, síbẹ̀síbẹ̀, ní wákàtí àìní ńlá Rẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ó sá Jesu tì tí wọ́n sì sálọ. Gbogbo wọn ló kùnà.
Mo gbàgbọ́ pé ọkàn nínú ìdí tí a fi sọ ìtàn ìkùnà Dafidi nínú gbogbo Ìwé ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní láti pè wá, gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, sí gbígba kókó àti òtítọ́ àwọn ìkùnà wa. Peteru, ọkàn nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi, kùnà. Mo lè kùnà. Ìwọpẹ̀lú lè kùnà. Gbogbo w ani a lè kùnà ní ọ̀nà kan tàbí òmírànàti pé ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà ṣẹ́ Kristi.
Ní kúkúrú, ìkùnà jẹ́ kókó ìgbésí-ayé Kristẹni wa tí ó yẹ ká gbà tí á sì fi òótọ́ inú kojúkọ, ní ọ̀nà kan náà ti Bíbélì gbà á tí ó sì dojú kọ ọ́ pẹ̀lú òtítọ́.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà ọlọ́jọ́-márùn-ún agbaní-níyànjú yìí ṣe àlàyé òtìtọ́ náà pé, nínú àṣẹ-ìdarí Rẹ̀, Ọlọ́run ti rí ìkùnà wa ṣáájú, àti pé nínú àánú Rẹ̀, ó dárí jin àwọn ìkùnà wa.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Returning to the Gospel - West Africa fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://returningtothegospel.com/