Àwọn Ìkùnà Wa Gẹ́gẹ́ bí KristẹniÀpẹrẹ
Ìfojú Ìhìnrere Wo Àwọn Ìkùnà Wa
Nígbà tí Peteru sọ fún Jesu, ‘Kódà bí gbogbo ènìyàn bá sá fún Ọ, n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láéláé,’ ó ń gbẹ́kẹ̀lé agbára àti àwọn èrò rere tirẹ̀ láti borí ìdanwò ẹ̀sẹ̀ yìí, àyọrísí ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni fún Peteru ni ìkùnà rẹ̀.
Ṣùgbọ́n ṣá, ní àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó gba agbára Ẹ̀mí Mímọ́, Peteru dìde níwájú àwọn aláṣẹ ẹ̀sìn Júù. Nígbà tí wọ́n ní kí ó síwọ́ ìwàásù ìhìnrere, ó fi ìgboyà sọ fún wọn pé òún gbà láti gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu dípò ènìyàn. Peteru kò gbẹ́kẹ̀lé okun ara ẹni tàbí àwọn èrò rere rẹ̀, èyí tí ó ti jẹ́ kó kùnà tẹ́lẹ̀; ní báyìí ó ń gbẹ́kẹ̀lé okun Kristi tí ó jíǹde, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi wọ̀ ọ́.
Èyí fi hàn pé nígbà tí a bá ń dojú kọ àwọn ìdanwò tí ó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìkùnà wa, a gbọ́dọ̀ képe Olúwa nínú àdúrà, kí á sì máa gbẹ́kẹ̀lé okun Rẹ̀ láti kó wa yọ.
Láti di Kristẹni, ohun àkọ́kọ́ tí a ṣe ni láti gbà àti láti jẹ́wọ́ pé a ti já Ọlọ́run kulẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a ti di Kristẹni, ó dàbí ohun tó kẹ́yìn tí a fẹ́ ṣe ni láti gbà pé a tún ń kùnà. Ó máa ń nira fún wa láti gbà pé a tún ń kùnà nígbà mìíràn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ kan náà.
Ó nira fún wa láti gbà pé ọ̀nà tí a máa ń sábà gbà ronú, tàbí ohun tí à ń wò nígbà tí a bá dá wà, tàbí ọ̀nà tí à ń gbà bá àwọn ènìyàn tó kù díẹ̀ káàtó fún lò nígbà mìíràn ṣe àfihàn ìkùnà láti gbé ìgbésí-ayé tó yẹ onígbàgbọ́ bi i wa.
Fún àwọn kan nínú wa, bóyá a tilẹ̀ ti kùnà ní ọ̀nà tí ó tì wá lójú. Ṣùgbọ́n rántí èyí, láìṣe peteru, o kò sí ní àgbàlá olórí àlùfáà. Rántí pé o kò sí nínú ìdẹwò, nítorí pé Kristi to ṣe èyí fún ọ.
Gẹ́gk bí Kristẹni, ó ní ìwàláàyè Ọlọ́run lójoojúmọ́, ẹni tí ó mọ ìkùnà rẹ ṣáájú, tí ó sì tún wá gbà ọ́ là. Èyí ni ìròyìn ayọ̀ ńlá ti ìhìnrere. Ó lè fi ìgbàgbọ́ gba ìdáríjìn tí í ṣe tìrẹ nínú Kristi kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Peteru ṣe ṣe, láti tẹ̀síwájú iṣẹ́ Rẹ̀ ojoojúmọ́ nínú ayé rẹ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, bí ó ṣe mú ọ dàgbà nínú ẹ̀mí.
Ó ṣe pàtàkì fún wa láti rántí pé àwọn ìkùnà wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti dárí rẹ̀ jìn wá, lè wá pẹ̀lú làásìgbò tí ó ń bá wọn rìn. Wọ́n lè bà wá jẹ́, wọ́n sì lè bá àwọn ìbáṣepọ̀ wa jẹ́, wọ́n sì lè fi àbàwọ́n sí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, ìtàn ìgbásí-ayé Peteru nínú Bíbélì ni ó ti ní àbàwọ́n títí láé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ síṣẹ́ Olúwa. Àwọn ìkùnà wa máa ń já àwọn ẹbí wa kulẹ̀, a sì ń fi àpẹẹrẹ burúkú lélẹ̀ fún àwọn ẹni tí ó ń wò wá gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe, bí àwọn ọmọ wa. Àwọn ìkùnà wa tún máa ń sọ ẹ̀sìn Kristẹni ní orúkọ burúkú láàrin àwọn aláìgbàgbọ́.
Nítorí náà, jọ̀wọ́, a kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìkùnà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, nítorí pé gbogbo ìgbà tí a bá kùnà, gẹ́gẹ́ bí Peteru nínú àyọkà yìí, ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, àwa náà ń ṣẹ́ Olúwa ni.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà ọlọ́jọ́-márùn-ún agbaní-níyànjú yìí ṣe àlàyé òtìtọ́ náà pé, nínú àṣẹ-ìdarí Rẹ̀, Ọlọ́run ti rí ìkùnà wa ṣáájú, àti pé nínú àánú Rẹ̀, ó dárí jin àwọn ìkùnà wa.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Returning to the Gospel - West Africa fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://returningtothegospel.com/