ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUNÀpẹrẹ

ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUN

Ọjọ́ 3 nínú 3

Wíwà nípa Ìgbàgbọ́

Ọ̀nà kan ṣoṣo tí onígbàgbọ́ fi le wà ni nípa ìgbàgbọ́. Romu 1:17 wí pé a fi Ọlọ́run hàn wá ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́. Èyí tú mọ̀ sí a ní àǹfààní láti mọ àdììtú àti òye ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí a ti ń dàgbà láti ìpele ìgbàgbọ́ kan sí òmíràn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹ̀síwájú láti sọ wí pé olódodo yóò wà nípa ìgbàgbọ́. Èyí tú mọ̀ sí pé ona kan tí a lè máa wà ni nípa gbígbé pátápátá nípa ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn baba ìgbàgbọ́ tí a ti dárúkọ ṣáájú kú sí orí dídi ìgbàgbọ́ wọn mú. Díẹ̀ lára wọn kò gbà ìlérí náà. Èyí ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe gbé ìgbé ayé ìfọkàntán àti ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Ọlọ́run. Ìyá mi a máa sọ fún wa nígbà tí à ń dàgbà pé a kò ní Ọlọ́run mìíràn leyin Ọlọ́run. Èyí fi ọkàn wa lé ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àjùlọ Ọlọ́run. Bí a ti sọ nípa àwọn akọni ìgbàgbọ́, wọ́n rí tayọ ayé yìí, wọn gbé ìgbé ayé ni ìrètí kíkún fún ayé tó tóbi tó sì dára ju èyí tí wọ́n wà nínú rẹ̀. Wọ́n gbé ìgbé ayé ìgbàgbọ́ kíkún ní ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run ti gbé ibi kan kalẹ̀ fún wọn leyin irin àjò wọn láyé yìí. Èyí ṣe àgbékalẹ̀ ìmọ̀ fún wọn èyí tí ó jẹ́ kí wọ́n rí kí wọ́n sì mọ̀ pé ayé àti ibi tó dára ṣì wà. Gbígbé ayé ẹni pẹ̀lú ìmọ̀ yìí jẹ́ nípa ìgbàgbọ́ nìkan.

Jésù Krístì nígbà tí ó wà láyé ṣe ìlérí ilé ńlá ní ọ̀run. Bí a kò tilẹ̀ tíì rí ilé yìí rí, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú rẹ̀ nítorí náà, a ń gbé ní ìrètí ọjọ́ tí a ó pàdé rẹ̀ ní ògo. A lè ṣe èyí nípa gbígbé nípa ìgbàgbọ́ kí a lè wọ ilé ńlá tí Ọlọ́run ṣèlérí.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUN

Ìrìn-àjò Kristẹni jẹ́ èyí tí a kò ti rí Ọlọ́run lójú-kojú, a máa ń bá A ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti wu Ọlọ́run nínú ìrìn wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ìgbàgbọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kò lè rí I pẹ̀lú ojú wa nípa tara. À ń gbọ́ Ọ nípa ìgbàgbọ́, à ń bá A sọ̀rọ̀ nípa Ìgbàgbọ́, a sì ń tọ̀ Ọ́ lọ nínú àdúrà nípa ìgbàgbọ́.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo:https://mountzionfilm.org/