ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUNÀpẹrẹ

ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUN

Ọjọ́ 2 nínú 3

Ìgbàgbọ́ àti Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run

Ó lè wu ni láti mọ̀ pé Ábúráhámù kò jẹ́ baba ìgbàgbọ́ lásán. Igbe ayé Ábúráhámù je àfihàn igbe ayé tí a ti jọ̀wọ́ pátápátá fún níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti gbígbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí rẹ̀.

Ní àkọ́kọ́ Ọlọ́run wí fún un pé kí ó fi ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ará rẹ sílẹ̀ àti kúrò ní ibí tí ó lè ti rí ogún àti ọjọ́ iwájú lọ sí ibi tí ó lè má ní ìrètí. Ní ìyàlẹ́nu, Ábúráhámù gbé ìgbésẹ̀ ìgboyà yìí. Mo pèé ní ìgbésẹ̀ ìgboyà nítorí n kò le wòye ẹni tí n kò rí kó máa fún wí fún mi pé kí n kúrò níbi tí mo mọ̀ lọ sí ibi tí kò dá mi lójú. Ó lè dára díẹ̀ bí mo bá mọ ibi tí mò ń lọ, mo lè ṣe ìwádìí tèmi kí n sì ṣètò ṣáájú ṣùgbọ́n fún ibi tí kò dá mi lójú, ìgbésẹ̀ ìgboyà ni lóòótọ́. Nígbà náà, Ábúráhámù nípa ìgbàgbọ́ gbé ní ibi yìí, ó sì tún bí ìran púpọ̀ sí ilẹ̀ àjòjì yìí.

Ọlọ́run tún ṣe ìlérí ọmọ fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ nígbà tí ó dàbí ẹni pé kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n nípa ìgbàgbọ́ Ábúráhámù àti Sárà di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú, wọ́n sì bí Ísákì ní ọjọ́ ogbó wọn. Ọlọ́run tún ṣe ìlérí pé àwọn ọmọ rẹ̀ yóò dàbí iyanrìn òkun àti bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

Àwọn àpẹẹrẹ méjì yìí ṣe àfihàn bí Ábúráhámù ṣe fi ìgbàgbọ́ hàn nípasẹ̀ ìgbọràn àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run èyí tí ó mú un wọ ìmúṣẹ. Yóò nira púpọ̀ láti wọ ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run fún wa bí a kò bá ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú kókó pé ó ti fún wa ní àwọn ìlérí yìí. Jákọ́bù 1 jẹ́ kí ó ye wa pé ọkàn oníyè méjì kò lè rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ ibi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run kí o lè gbádùn ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ fún wa.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUN

Ìrìn-àjò Kristẹni jẹ́ èyí tí a kò ti rí Ọlọ́run lójú-kojú, a máa ń bá A ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti wu Ọlọ́run nínú ìrìn wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ìgbàgbọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kò lè rí I pẹ̀lú ojú wa nípa tara. À ń gbọ́ Ọ nípa ìgbàgbọ́, à ń bá A sọ̀rọ̀ nípa Ìgbàgbọ́, a sì ń tọ̀ Ọ́ lọ nínú àdúrà nípa ìgbàgbọ́.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo:https://mountzionfilm.org/