Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Tí Yíó Yí Ayé Rẹ PadàÀpẹrẹ
Agbára Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan
Ṣètò
Ìpinnu Ọdún Tuntun kìí ṣiṣẹ́!
Awọn ipinnu Ọdun Tuntun ko ṣiṣẹ!< / p > < p > aadọta ogorun ti awọn oluṣe ipinnu kuna ni opin Oṣu Kini ati 9 ninu 10 kuro ni Oṣu Kẹta! Nitorinaa dipo awọn ipinnu, gba Ọrọ Kan fun ọdun... ṣugbọn ṣọra! O le kan yi o.
Bí èròngbà ọkàn rẹ báni "ó gbọdọ̀ jẹ́ ṣíṣe" bíi ti tàwa náà, o ti kó ipa tìrẹ nínú ṣíṣe àgbékalẹ̀ àfojúsùn ní ìbẹ̀rẹ̀ Ọdún Tuntun kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀wẹ̀, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a máa tọjú sú wa bí a kò bá kún ojú òṣùwọ̀n àwọn ètó èròngbà ńláńlá wa. A máa ń fẹ́ ṣe àṣejù, látàrí èyí a kìí ṣe ohunkóhun bó tí tọ́ àti bó ti yẹ.
Ní ọdún 1999, a bẹ̀rẹ̀ ìfarajì kí a máa ṣe ágbékalẹ̀ Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan fún ọdún tó ń bọ̀. Bẹ́ẹ̀ni -Ọ̀rọ̀ Kan. Kìì ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn, ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ni. Nípa fífojúsí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan, a ti ní ìrírí ìyípadà aláìlẹ́gbẹ́ nínú ayé wa lọ́dọọdún. Nígbàtí o bá ṣ'àwárí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan tìrẹ fún ọdún, yíó fún ọ ní òye kedere, ìtara àti èrèdí fún ayé rẹ.
Ṣíṣe àmúlò Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan yìí maá ń mú ìrọ̀rùn àti àfojúsùn wá. A máa gé ìdènà kúrò, a sì máa mú wa fojúsí ohun tó ṣe pàtàkí jù. O tí pè wá níjà ní gbogbo ọ̀nà: l'ẹ́mìí, l'ára, l'érò-ọkàn, l'érò-ara, nínú ìbájọṣepọ̀ àti nínú ètò ìsúúná. Ọlọ́run ti yí wa padà nípa ìgbésẹ̀ yìí, inú Ọlọ́run dùn sí ìgbé-ayé tó yípadà.
Ó ní ìdí tí a fi ń sọ pé, "Ṣ'àwàrí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan fún gbogbo ọdún…ṣùgbọ́n kíyèsára.” Ní kété tí o bá ti ṣ'àwárí ọ̀rọ̀ rẹ, ogun bẹ̀rẹ̀. Èyí a máa mú ìgbésẹ̀ ẹ̀kọ́, ìdàgbàsóké, àtúnṣe, àti àtúnmọ lọ́wọ́. Ọlọ́run yíó lo ọ̀rọ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bíi fìtílà àti dígí- tí ń tan ìmọ́lẹ̀ s'ípa ọ̀nà rẹ tó sì ń fí gbogbo ohun tó níilò àtúnṣe hàn. Áa ṣe okùnfà ìrìn-àjò ìlọsókè-lọsódò tí èrèdí rẹ̀ jẹ́ láti sọ ọ́ di ẹni tí a dá ọ láti jẹ́.
Ìrírí wa ni pé Ọlọ́run ń tètè maá ń ṣe àfihàn ètò Rẹ̀ fún ọdún nípa Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ. Ọ̀rọ̀ yìí (ì báà jẹ́ ìbáwí, èso Ẹ̀mí, ìhùwàsí, tàbí àbùdá Ọlọ́run) yíó ṣ'àmì sí ọ fún gbogbo ọdún! Nítorí náà ṣ'àwárí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan tìrẹ fún ọdún kí o sì ṣe àjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn! Ó kàn lè yí ayé rẹ padà!
Lọ
1. Kíni Ọlọ́run ń bá ọ sọ ní ọdún tó kọjá yìí?
2. Àwọn ibo ni Ọlọ́run ti fẹ́ kí o ṣàkóso ayé rẹ kí o sì lòó fún ògo Rẹ̀?
3. Báwo ní Ọlọ́run ṣe fẹ́ gbé ọ kalẹ̀ fún ọdún tó ń bọ̀?
Ṣiṣẹ́ tọ
Sáàmù 27:1-14; Lúùkū 18:22; Máàkù 10:21
Àlékún
"Olúwa Rere, mo bèèrè pé kí O ṣe ọdún yìí ní èyí tí ó ń yí'ni padà. Fi ara Rẹ hàn fún mi bí O tí ń fi ohun tí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan yíó jẹ́ hàn mí. Fi Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ kún mi. Mo mọ̀ pé ìrìn-àjò ẹ̀kọ́ ni kìí ṣe iṣẹ́ tó ní gbèdéke ibi tó parí sí. Fún mi ní okun bí màá ṣe máa gbé ìgbé-aye Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan mi lójoojúmọ́. Ní orúkọ Jésù, àmín."
Ṣé o fẹ́ Ètò Ìgbésẹ̀ Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan? Ṣe àgbàsílẹ̀ rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ ní GetOneWord.com
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ayé rẹ rọrùn nípa f'ífojúsí KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN fún gbogbo ọdún. Ìrọ̀rùn tó wà nínú ṣíṣe àwárí ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run ní fún ọ jẹ́ kí ó jẹ́ kóríyá fún ìgbé-ayé ọ̀tọ̀. Wúruwùru àti ìdíjúpọ̀ ma ń ṣe okùnfà ìlọ́ra àti ìdálọ́wọ́kọ́, nígbàtí ìrọ̀rùn àti àfojúsùn a maá yọrí sí àṣeyọrí àti ìjágaara. Ètò-ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yíó fi bí a ti ń la aàrín gbùngbùn àníyàn rẹ kọjá láti ṣe àwárí ìran kìkì ọ̀rọ̀ fún gbogbo ọdún.
More