Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Tí Yíó Yí Ayé Rẹ PadàÀpẹrẹ
Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Péré
Ṣètò
Kò rọrùn láti sọ ayé d'ìrọ̀rùn. Pípa ọkàn pọ̀ s'ójúkan jọ ohun kòṣeéṣe. Láàrin ọdún tí a lò tán yìí, a lè ti bi ọ́ l'ọ́pọ̀ ìgbà pé, 'Báwo ló ṣe ńlọ?" Èsì rẹ jọ bí ẹni pé ó lọ báyìí, "Iṣè ti mu mí l'ómi JÙ!" A kìí gbọ́ kí ẹnikẹni sọ pé, “Mo ní àsìkò púpọ̀ débii pé mò ń wá ǹǹkan tuntun láti ṣe.” Kò sí irú ènìyàn báyìí.
O ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe, àti pé ètò iṣẹ́ rẹ pakasọ. Ó jọ bíi pé ò ń s'áré ìje nínú ayé. Ìdí nìyìí tí a fi gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ mú kí ayé rọrùn kí ó sì yè kooro. A ti ń ṣe àjọpín pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn bí a ṣe ń ṣe àgbékalẹ̀ kìkì ọ̀rọ̀ kan bíi kókó àfojúsùn fún ọdún tó ń bọ̀. A pinnu láti dáwọ́ kíkọ ìpinnu ọdún tuntun sílẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀ síí gbé ìgbé-ayé Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò ní àkosílẹ̀ "Ètò Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan," o jọ ni lójú pé gbólóhùn "ohun kan" jẹyọ bíi ìgbà márùn-ún nínú Bíbélì: lẹ́ẹ̀kan nínú ìwé Fílípì àti lẹ́ẹ̀mẹrin nínú ìwé Ìhìnrere.
Nínú Fílípì 3:13-14, Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn "ohun kan" láti mú àfòjúsùn àti òye òkodooro bá ìpè rẹ̀. Nínú Lúùkù 10:42, Jésù sọ fún Martha pé, "ohun kan ṣoṣo ni a kò lè ṣe aláìní." Àti Lúùkù 18:22 pẹ̀lú Máàkù 10:21 ló ní àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ nì tí wọn sì ṣe àfihàn àìní "ohun kan." Jòhánù 9:25 náà lo gbólóhùn yìí bí ọkùnrin afọ́jú ṣe ń sọ fún àwọn Farisí pé, "ohun kan ni mo mọ̀. Mo ti fọ́jú rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo ríran!" Bí Ìwé-Mímọ́ ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí náà ni àwa náà lè lòó nìpa bíbéèrè pé kí Ọlọ́run ṣe àfihàn kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan fún wa fún gbogbo ọdún.
Nígbàtí a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìlànà yìí, ìlàjì ohun kóríyá ibẹ̀ ni pípinnu ọ̀rọ̀ náà fún ọdún, ṣùgbọ́n a tí kẹ́kọ̀ọ́ pé kìí ṣe àwa ni a gbọ́dọ̀ yan ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní Ó maá ń fihàn wá. Ọlọ́run lè dìídì fi àṣànyàn ọ̀rọ̀ àmì-òróró kan sí ọ l'ọ́kàn. Ní àwọn ọdún péréte àkọ́kọ́, a gbà pé àwa ni a kàn ń mú àwọn ọ̀rọ̀ kan ṣáá, láì gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ọgbaa bẹ́ẹ̀ náà, Ọlọ̀run sì lòó! Ṣùgbọ́n bí a ṣe ń ní ìrírí síi nínú ìlànà yìí, a kọ́ láti máa t'ẹ́tí sílẹ̀ kí á sì w'ọ̀nà fùn ìtọ́ni Ọlọ̀run nínú yíyan ọ̀rọ̀ náà. Nípa títẹ́tísí ohùn Ọlọ́run, oó ṣe àwárí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run, kìí kàn án ṣe ọ̀rọ̀ dáadáa kan sáá.
Jẹ ìgbádùn ìlànà yìí kí o sì rántí pé: Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan péré. Kìí ṣe gbólóhùn. Kìí sìí ṣe ọ̀rọ̀ méjì. Pa ọkàn pọ̀ sójú kan fún àyípadà nínú ìgbé-ayé. Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Pérè!
Lọ
1. Kílódé tó jẹ́ pé kò rọrùn láti mú ayé rọrùn? Kíni ìdí rẹ̀ tí ayé fi díjú pọ̀ bẹ́ẹ̀?
2. Kíni o rò pé ó fàá tí a ṣe ń fẹ́ tẹ́ àwọn ènìyàn lọ́rùn pẹ̀lù ohun púpọ̀ tí kìí ṣe ohun díẹ̀?
3. Kíni ohun tí Ọlọ́run ń bá ọ sọ nípa kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan tìrẹ fún gbogbo ọdún? Lo àsìkò tó péye láti gbàdúrà kí o sì bèèrè pé kí Ọlọ́run bá ọ sọ̀rọ̀.
Ṣiṣẹ́ tọ
Hébérù 12:1-2, Jòhánù 9:25, Fílípì 3:13-14
Àlékún
"Baba Tòótọ́ tí ńbẹ ní Ọ̀run, mò ńbèèrè fún Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan. Mo fẹ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Jọ̀wọ́ fi ara Rẹ hàn mí. Mo ṣetàn láti gba ọ̀rọ̀ tí ó yẹ fún mi. Ní orúkọ Jésù, àmín."
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ayé rẹ rọrùn nípa f'ífojúsí KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN fún gbogbo ọdún. Ìrọ̀rùn tó wà nínú ṣíṣe àwárí ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run ní fún ọ jẹ́ kí ó jẹ́ kóríyá fún ìgbé-ayé ọ̀tọ̀. Wúruwùru àti ìdíjúpọ̀ ma ń ṣe okùnfà ìlọ́ra àti ìdálọ́wọ́kọ́, nígbàtí ìrọ̀rùn àti àfojúsùn a maá yọrí sí àṣeyọrí àti ìjágaara. Ètò-ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yíó fi bí a ti ń la aàrín gbùngbùn àníyàn rẹ kọjá láti ṣe àwárí ìran kìkì ọ̀rọ̀ fún gbogbo ọdún.
More