1
ORIN DAFIDI 103:2
Yoruba Bible
Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:2
2
ORIN DAFIDI 103:3-5
ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:3-5
3
ORIN DAFIDI 103:1
Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:1
4
ORIN DAFIDI 103:13
Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:13
5
ORIN DAFIDI 103:12
Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:12
6
ORIN DAFIDI 103:8
Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:8
7
ORIN DAFIDI 103:10-11
Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:10-11
8
ORIN DAFIDI 103:19
OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, ó sì jọba lórí ohun gbogbo.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 103:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò