1
Oniwaasu 10:10
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Bí àáké bá kú tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n; yóò nílò agbára púpọ̀ ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Oniwaasu 10:10
2
Oniwaasu 10:4
Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ, ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀; ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.
Ṣàwárí Oniwaasu 10:4
3
Oniwaasu 10:1
Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú, bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.
Ṣàwárí Oniwaasu 10:1
4
Oniwaasu 10:12
Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.
Ṣàwárí Oniwaasu 10:12
5
Oniwaasu 10:8
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.
Ṣàwárí Oniwaasu 10:8
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò