AISAYA 46:10-11

AISAYA 46:10-11 YCE

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn. Láti ìgbà àtijọ́, ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀. Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ, n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’ Mo pe idì láti ìlà oòrùn, mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá. Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ, mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é.