Isaiah 46:10-11

Isaiah 46:10-11 YCB

Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé: Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí. Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ; èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.