ÌWÉ ÒWE 18
18
1Onímọ-tara-ẹni-nìkan ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀,
láti tako ìdájọ́ òtítọ́.
2Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀,
àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.
3Nígbà tí ìwà burúkú bá dé, ẹ̀gàn yóo dé,
bí àbùkù bá wọlé ìtìjú yóo tẹ̀lé e.
4Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan dàbí odò jíjìn,
orísun ọgbọ́n dàbí omi odò tí ń tú jáde.
5Kò dára kí á ṣe ojuṣaaju sí eniyan burúkú,
tabi kí á dá olódodo ní ẹjọ́ ẹ̀bi.
6Ẹnu òmùgọ̀ a máa dá ìjà sílẹ̀,
ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ a sì máa bá a wá pàṣán.
7Ẹnu òmùgọ̀ ni yóo tì í sinu ìparun,
ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ni yóo sì ṣe tàkúté mú un.
8Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùn,
a máa wọni lára ṣinṣin.
9Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,
ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.
10Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára,
olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.
11Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,
lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.
12Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,
ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.
13Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, #Sir 11:18
kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.
14Eniyan lè farada àìsàn,
ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?
15Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀,
etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri.
16Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn,
a sì mú un dé iwájú ẹni gíga.
17Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre,
títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè,
18Gègé ṣíṣẹ́ a máa yanjú ọ̀rọ̀
a sì parí gbolohun asọ̀ láàrin àwọn alágbára.
19Ọkàn arakunrin tí eniyan bá ṣẹ̀ a máa le bí ìlú olódi,
àríyànjiyàn sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ilé ìṣọ́.
20Eniyan lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá oúnjẹ fún ara rẹ̀,
a lè jẹ oúnjẹ tí a bá fi ọ̀rọ̀ ẹnu wá
ní àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù.
21Ahọ́n lágbára láti pani ati láti lani,
ẹni tí ó bá fẹ́ràn rẹ̀ yóo jèrè rẹ̀.
22Ẹni tí ó bá rí aya fẹ́ rí ohun rere, #Sir 26:1-4
ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA.
23Ẹ̀bẹ̀ ni talaka bẹ̀,
ṣugbọn ọlọ́rọ̀ á dáhùn tìkanra-tìkanra.
24Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n,
ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 18: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010