1
ÌWÉ ÒWE 18:21
Yoruba Bible
Ahọ́n lágbára láti pani ati láti lani, ẹni tí ó bá fẹ́ràn rẹ̀ yóo jèrè rẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:21
2
ÌWÉ ÒWE 18:10
Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára, olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:10
3
ÌWÉ ÒWE 18:24
Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n, ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:24
4
ÌWÉ ÒWE 18:22
Ẹni tí ó bá rí aya fẹ́ rí ohun rere, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:22
5
ÌWÉ ÒWE 18:13
Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:13
6
ÌWÉ ÒWE 18:2
Òmùgọ̀ kò ní inú dídùn sí ìmọ̀, àfi kí ó ṣá máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:2
7
ÌWÉ ÒWE 18:12
Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun, ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.
Ṣàwárí ÌWÉ ÒWE 18:12
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò