ÌWÉ ÒWE 19

19
1Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú,
ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ.
2Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀,
ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà.
3Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a,
ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú.
4Ọrọ̀ a máa mú kí eniyan ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ titun,
ṣugbọn àwọn ọ̀rẹ́ talaka a máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
5Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,
bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀san ibi.
6Ọ̀pọ̀ eniyan níí máa ń wá ojurere ẹni tó lawọ́,
gbogbo eniyan sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn.
7Gbogbo àwọn arakunrin talaka ni wọ́n kórìíra rẹ̀,
kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jìnnà sí i!
Ó fọ̀rọ̀ ẹnu fà wọ́n títí, sibẹ wọn kò súnmọ́ ọn.
8Ẹni tí ó ní ọgbọ́n fẹ́ràn ara rẹ̀,
ẹni tí ó bá sì ní òye, yóo ṣe rere.
9Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,
ẹni tí ó ń pa irọ́ yóo parun.
10Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè.
11Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú,
ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá.
12Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun,
ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.
13Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀,
iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró.
14A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni,
ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere.
15Ìwà ọ̀lẹ a máa múni sùn fọnfọn,
ebi níí sìí pa alápá-má-ṣiṣẹ́.
16Ẹni tí ó bá pa òfin mọ́, ẹ̀mí ara rẹ̀ ni ó pamọ́,
ẹni tí ó kọ ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀ yóo kú.
17Ẹni tí ó ṣe ojurere fún àwọn talaka, OLUWA ni ó ṣe é fún,
OLUWA yóo sì san ẹ̀san rẹ̀ fún un.
18Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ó sì lè gbọ́ ìbáwí,
má sì ṣe wá ìparun rẹ̀.
19Onínúfùfù yóo jìyà inúfùfù rẹ̀,
bí o bá gbà á sílẹ̀ lónìí, o níláti tún gbà á sílẹ̀ lọ́la.
20Gbọ́ ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́,
kí o lè rí ọgbọ́n lò lẹ́yìn ọ̀la.
21Ọpọlọpọ ni èrò tí ó wà lọ́kàn ọmọ eniyan,
ṣugbọn ìfẹ́ OLUWA ni àṣẹ.
22Ohun tí ayé ń fẹ́ lára eniyan ni òtítọ́ inú,
talaka sì sàn ju òpùrọ́ lọ.
23Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú ìyè wá,
ẹni tí ó ní i yóo ní ìfọ̀kànbalẹ̀,
ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí i.
24Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,
ṣugbọn kò lè bu oúnjẹ sí ẹnu ara rẹ̀.
25Na pẹ̀gànpẹ̀gàn eniyan, òpè yóo sì kọ́gbọ́n.
Bá olóye wí, yóo sì ní ìmọ̀ sí i.
26Ẹni tí ó bá kó baba rẹ̀ nílé, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde,
ọmọ tíí fa ìtìjú ati àbùkù báni ni.
27Ọmọ mi, bí o bá kọ etí dídi sí ẹ̀kọ́,
o óo ṣìnà kúrò ninu ìmọ̀.
28Ẹlẹ́rìí èké a máa kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́,
eniyan burúkú a máa jẹ ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni jẹun.
29Ìjìyà ti wà nílẹ̀ fún ẹlẹ́yà,
a sì ti tọ́jú pàṣán sílẹ̀ fún ẹ̀yìn òmùgọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀