Hab 3:17-18

Hab 3:17-18 YBCV

Bi igi ọpọ̀tọ kì yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko kì yio si mu onje wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ́ ẹran kì yio si si ni ibùso mọ: Ṣugbọn emi o ma yọ̀ ninu Oluwa, emi o ma yọ̀ ninu Ọlọrun igbàla mi.