Habakuku 3:17-18

Habakuku 3:17-18 YCB

Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà; tí igi olifi ko le so, àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá; tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́, síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú OLúWA, èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.