O. Daf 10

10
Adura Olùpọ́njú
1EṢE ti iwọ fi duro li òkere rere, Oluwa; ẽṣe ti iwọ fi fi ara pamọ́ ni igba ipọnju.
2Ninu igberaga li enia buburu nṣe inunibini si awọn talaka: ninu arekereke ti nwọn rò ni ki a ti mu wọn.
3Nitori enia buburu nṣogo ifẹ ọkàn rẹ̀, o si nsure fun olojukokoro, o si nkẹgan Oluwa.
4Enia buburu, nipa igberaga oju rẹ̀, kò fẹ ṣe afẹri Ọlọrun: Ọlọrun kò si ni gbogbo ironu rẹ̀.
5Ọ̀na rẹ̀ nlọ siwaju nigbagbogbo; idajọ rẹ jina rere kuro li oju rẹ̀; gbogbo awọn ọta rẹ̀ li o nfẹ̀ si.
6O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, A kì yio ṣi mi ni ipò: lati irandiran emi kì yio si ninu ipọnju.
7Ẹnu rẹ̀ kún fun egún, ati fun ẹ̀tan, ati fun itanjẹ: ìwa-ìka ati ìwa-asan mbẹ labẹ ahọn rẹ̀.
8O joko ni buba ni ileto wọnni: ni ibi ìkọkọ wọnni li o npa awọn alaiṣẹ̀: oju rẹ̀ nṣọ́ awọn talaka nikọkọ.
9O lùmọ ni ibi ìkọkọ bi kiniun ninu pantiri: o lùmọ lati mu talaka: a si mu talaka, nigbati o ba fà a sinu àwọn rẹ̀.
10O ba, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ki talaka ki o le bọ́ si ọwọ agbara rẹ̀.
11O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun ti gbagbe: o pa oju rẹ̀ mọ́; on kì yio ri i lailai.
12Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju.
13Ẽṣe ti enia buburu fi ngàn Ọlọrun? o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Iwọ kì yio bère.
14Iwọ ti ri i; nitori iwọ nwò ìwa-ìka ati iwọsi, lati fi ọ̀ran na le ọwọ rẹ; talaka fi ara rẹ̀ le ọ lọwọ; iwọ li oluranlọwọ alaini-baba.
15Ṣẹ́ apa enia buburu, ati ti ọkunrin ibi nì: iwọ wá ìwa-buburu rẹ̀ ri, titi iwọ kì yio fi ri i mọ́.
16Oluwa li ọba lai ati lailai: awọn keferi run kuro ni ilẹ rẹ̀.
17Oluwa, iwọ ti gbọ́ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i.
18Lati ṣe idajọ alaini-baba ati ẹni-inilara, ki ọkunrin aiye ki o máṣe daiya-fo-ni mọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 10: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀