O. Daf 11
11
OLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo
1OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin?
2Sa kiyesi i, awọn enia buburu ti fà ọrun wọn le, nwọn ti fi ọfa sùn li oju ọṣán, ki nwọn ki o le ta a li òkunkun si ọlọkàn diduro.
3Bi ipilẹ ba bajẹ, kili olododo yio ṣe?
4Oluwa mbẹ ninu tempili mimọ́ rẹ̀, itẹ́ Oluwa mbẹ li ọrun: oju rẹ̀ nwò, ipenpeju rẹ̀ ndán awọn ọmọ enia wò.
5Oluwa ndán olododo wò: ṣugbọn enia buburu ati ẹniti nfẹ ìwa-agbara, ọkàn rẹ̀ korira.
6Lori enia buburu ni yio rọjo, ẹyín gbigbona ati imi-ọjọ ati iji gbigbona: eyi ni ipin ago wọn.
7Nitori olododo li Oluwa, o fẹ ododo; awọn ẹniti o duro-ṣinṣin yio ri oju rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.