O. Daf 77
77
Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú
1EMI fi ohùn mi kigbe si Ọlọrun, ani si Ọlọrun ni mo fi ohùn mi kepè; o si fi eti si mi.
2Li ọjọ ipọnju mi emi ṣe afẹri Ọlọrun: ọwọ mi nnà li oru, kò si rẹ̀ silẹ: ọkàn mi kọ̀ ati tù ninu.
3Emi ranti Ọlọrun, emi kẹdun: emi ṣe aroye, ẹmi mi si rẹ̀wẹsi.
4Iwọ kò fẹ ki emi ki o fi oju ba orun: ẹnu yọ mi tobẹ̃ ti emi kò le sọ̀rọ.
5Emi ti nrò ọjọ atijọ, ọdun igbani.
6Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ.
7Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́?
8Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai?
9Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́?
10Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo!
11Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ.
12Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ.
13Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun?
14Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia.
15Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu.
16Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ.
17Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu.
18Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì.
19Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀.
20Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 77: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.