O. Daf 78
78
Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀
1FI eti silẹ, ẹnyin enia mi, si ofin mi: dẹ eti nyin silẹ si ọ̀rọ ẹnu mi.
2Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade.
3Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa.
4Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ.
5Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn.
6Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn:
7Ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rẹ̀ mọ́.
8Ki nwọn ki o máṣe dabi awọn baba wọn, iran alagidi ati ọlọ̀tẹ̀; iran ti kò fi ọkàn wọn le otitọ, ati ẹmi ẹniti kò ba Ọlọrun duro ṣinṣin.
9Awọn ọmọ Efraimu ti o hamọra ogun, ti nwọn mu ọrun, nwọn yipada li ọjọ ogun.
10Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, nwọn si kọ̀ lati ma rìn ninu ofin rẹ̀.
11Nwọn si gbagbe iṣẹ rẹ̀, ati ohun iyanu rẹ̀, ti o ti fi hàn fun wọn.
12Ohun iyanu ti o ṣe niwaju awọn baba wọn ni ilẹ Egipti, ani ni igbẹ Soani.
13O pin okun ni ìya, o si mu wọn là a ja; o si mu omi duro bi bèbe.
14Li ọsan pẹlu o fi awọsanma ṣe amọna wọn, ati li oru gbogbo pẹlu imọlẹ iná.
15O sán apata li aginju, o si fun wọn li omi mímu lọpọlọpọ bi ẹnipe lati inu ibú wá.
16O si mu iṣàn-omi jade wá lati inu apata, o si mu omi ṣàn silẹ bi odò nla.
17Nwọn si tún ṣẹ̀ si i; ni ṣiṣọtẹ si Ọga-ogo li aginju.
18Nwọn si dán Ọlọrun wò li ọkàn wọn, ni bibère onjẹ fun ifẹkufẹ wọn.
19Nwọn si sọ̀rọ si Ọlọrun; nwọn wipe, Ọlọrun ha le tẹ́ tabili li aginju?
20Wò o! o lù apata, omi si tú jade, iṣàn-omi si kún pupọ; o ha le funni li àkara pẹlu? o ha le pèse ẹran fun awọn enia rẹ̀?
21Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli;
22Nitori ti nwọn kò gbà Ọlọrun gbọ́, nwọn kò si gbẹkẹle igbala rẹ̀.
23O paṣẹ fun awọsanma lati òke wá, o si ṣi ilẹkùn ọrun silẹ.
24O si rọ̀jo Manna silẹ fun wọn ni jijẹ, o si fun wọn li ọkà ọrun.
25Enia jẹ onjẹ awọn angeli; o rán onjẹ si wọn li ajẹyo.
26O mu afẹfẹ ìla-õrun fẹ li ọrun, ati nipa agbara rẹ̀ o mu afẹfẹ gusu wá.
27O rọ̀jo ẹran si wọn pẹlu bi erupẹ ilẹ, ati ẹiyẹ abiyẹ bi iyanrin okun.
28O si jẹ ki o bọ́ si ãrin ibudo wọn, yi agọ wọn ka.
29Bẹ̃ni nwọn jẹ, nwọn si yo jọjọ: nitoriti o fi ifẹ wọn fun wọn.
30Nwọn kò kuro ninu ifẹkufẹ wọn; nigbati onjẹ wọn si wà li ẹnu wọn.
31Ibinu Ọlọrun de si ori wọn, o pa awọn ti o sanra ninu wọn, o si lù awọn ọdọmọkunrin Israeli bolẹ.
32Ninu gbogbo wọnyi nwọn nṣẹ̀ siwaju, nwọn kò si gbà iṣẹ iyanu rẹ̀ gbọ́.
33Nitorina li o ṣe run ọjọ wọn li asan, ati ọdun wọn ni ijaiya.
34Nigbati o pa wọn, nigbana ni nwọn wá a kiri: nwọn si pada, nwọn bère Ọlọrun lakokò,
35Nwọn si ranti pe, Ọlọrun li apata wọn, ati Ọlọrun Ọga-ogo li Oludande wọn,
36Ṣugbọn ẹnu wọn ni nwọn fi pọ́n ọ, nwọn si fi ahọn wọn ṣeke si i.
37Nitori ọkàn wọn kò ṣe dẽde pẹlu rẹ̀, bẹ̃ni nwọn kò si duro ṣinṣin ni majẹmu rẹ̀.
38Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke.
39Nitoriti o ranti pe, enia ṣa ni nwọn; afẹfẹ ti nkọja lọ, ti kò si tun pada wá mọ.
40Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ!
41Nitõtọ, nwọn yipada, nwọn si dan Ọlọrun wò, nwọn si ṣe aropin Ẹni-Mimọ́ Israeli.
42Nwọn kò ranti ọwọ rẹ̀, tabi ọjọ nì ti o gbà wọn lọwọ ọta.
43Bi o ti ṣe iṣẹ-àmi rẹ̀ ni Egipti, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ni igbẹ Soani.
44Ti o si sọ odò wọn di ẹ̀jẹ; ati omi ṣiṣan wọn, ti nwọn kò fi le mu u.
45O rán eṣinṣin sinu wọn, ti o jẹ wọn; ati ọpọlọ, ti o run wọn.
46O fi eso ilẹ wọn fun kokoro pẹlu, ati iṣẹ wọn fun ẽṣú.
47O fi yinyin pa àjara wọn, o si fi yinyin nla pa igi sikamore wọn.
48O fi ohun ọ̀sin wọn pẹlu fun yinyin, ati agbo-ẹran wọn fun manamana.
49O mu kikoro ibinu rẹ̀ wá si wọn lara, irunu ati ikannu, ati ipọnju, nipa riran angeli ibi sinu wọn.
50O ṣina silẹ fun ibinu rẹ̀; kò da ọkàn wọn si lọwọ ikú, ṣugbọn o fi ẹmi wọn fun àjakalẹ-àrun.
51O si kọlu gbogbo awọn akọbi ni Egipti, olori agbara wọn ninu agọ Hamu:
52Ṣugbọn o mu awọn enia tirẹ̀ lọ bi agutan, o si ṣe itọju wọn ni iju bi agbo-ẹran.
53O si ṣe amọna wọn li alafia, bẹ̃ni nwọn kò si bẹ̀ru: ṣugbọn okun bò awọn ọta wọn mọlẹ.
54O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà.
55O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn.
56Ṣugbọn nwọn dan a wò, nwọn si ṣọ̀tẹ si Ọlọrun Ọga-ogo, nwọn kò si pa ẹri rẹ̀ mọ́.
57Ṣugbọn nwọn yipada, nwọn ṣe alaiṣotitọ bi awọn baba wọn: nwọn si pẹhinda si apakan bi ọrun ẹ̀tan.
58Nitori ti nwọn fi ibi giga wọn bi i ninu, nwọn si fi ere finfin wọn mu u jowu.
59Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi.
60Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia.
61O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì.
62O fi awọn enia rẹ̀ fun idà pẹlu; o si binu si ilẹ-ini rẹ̀.
63Iná run awọn ọdọmọkunrin wọn; a kò si fi orin sin awọn wundia wọn ni iyawo.
64Awọn alufa wọn ti oju idà ṣubu; awọn opó wọn kò si pohunrere ẹkún.
65Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini.
66O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye.
67Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu:
68Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ.
69O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai.
70O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá:
71Lati má tọ̀ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ́ Jakobu, enia rẹ̀, ati Israeli, ilẹ-ini rẹ̀.
72Bẹ̃li o bọ́ wọn gẹgẹ bi ìwa-titọ inu rẹ̀; o si fi ọgbọ́n ọwọ rẹ̀ ṣe amọna wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 78: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.