Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 14 nínú 25

Àlàáfíà Ète Àtọ̀runwá

Ìbèrù lè dáwó è dúró ní ònà e,o lè mú o sáré àti fara pa mó. Sátánì nífẹ̀ẹ́ láti fún wa ní ìpínyà ọkàn pèlú ìbẹ̀rù láti fà wa sẹ́yìn kúrò nínú rírí ààbò ìtọ́sọ́nà Olórun. Ìbèrù halẹ̀ mọ́ ìmúṣẹ Kérésìmesì nígbà púpò, àtipe Olórun mọ̀ọ́mọ̀ ràn àwon èdá pàtàkì itàn Rè léti léraléra, “Má se fòyà.”

Mátíù 1:18-21 so apá Jósẹ́fù nínú itàn Kérésìmesì. Màríà lóyún kí òun àti Jósẹ́fù tó se ìgbéyàwó, àtipe Jósẹ́fù, “jé o̩kùnrin olódodo àtipe kò fé dójú ti i, sètò láti lé jáde ní bòókẹ́lẹ́.” Àmó àngélì láti òdò Olórun fara hàn sí i nínú àlá, o fi lọ́kàn balẹ̀, pé a ti yàn láti tó Omo Olórun lórí ilè-ayé.

Jósẹ́fù nígbà àkọ́kọ́ hùwà pa dà sí ìròyìn oyún Màríà nípa gbígbìyànjú láti pa orúkọ rere tí ara rè àti Màríà mó, ìbèrù gbogbo àwon ìtùmò. Kò ní ònà láti mò bóyá èrí wúńdíá Màríà bófin mu, àtipe o fé fòpin sí ìdánaàdéhùn ìgbéyàwó. láàárín àkókò,ìrora àti ìdàrúdàpọ̀ fún Jósẹ́fù, Olórun wá sódò rè nínú àlá, Ó pè ìbèrù rè níjà pèlú àlàáfíà ète àtọ̀runwá, àtipe fi i kalè sórí ipa ònà láti jé bàbá tí ayé Okùnrin tó ga jù lo tí gbogbo ayé mò.

Ní àwon àkókò ìbèrù wa, Olórun fé sò òtítọ́ sí wa àti tú agbára iró ohun yòó wù tón fawa sẹ́yìn ká. Nígbà tí a bá wá àlàáfíà Rè, O máa ṣẹ́gun àwon ìbèrù wa pèlú ifé Rè. Béèrè láti ọ̀dọ̀ Olórun láti wá àti sò òtítọ́ si ohun yòó wù iró tón fún ó ní àníyàn lónìí. Yóò jé olódodo láti fèsì àti kún ó ní agbára láti tésíwájú sínú ète àràmàndà tí O ní fún è.

Àdúrà: Bàbá, Òrò Yín so wipé È kò fún wa ni èmí ìbèrù, àmó tí agbára, àti ifé, àti èmí tó yè kooro. È seun fún fifún mi ní gbogbo ohun tí mo nílò láti máa tésíwájú nígbà tí òtá gbìyànjú láti fawa séyìn. Mo yìn Yín pé ìbèrù ní láti forí balẹ̀ fún orúko Jésù. Láàárín àkókò Kérésimèsì yìí, àti nígbà gbogbo, È ràn mi lówó láti mú àwon èrò ìbèrù ìgbèkùn àti lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mú wón sódò Yín kí àlàáfíà lè joba nínú ayé mi.

Gbà àwòrán tónìí jáde níbí.

Ọjọ́ 13Ọjọ́ 15

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/