Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 1 nínú 25

Ìlérí Ìṣáájú

Ǹjẹ́ o mọ̀ wípé ìlérí àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ṣe dá lórí Kérésìmesì? Nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, a kà wípé nígbà tí Ádámù àti Éfà kọ́kọ́ d'ẹ́ṣẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, ẹ̀dá ènìyàn yapa kúrò ní wájú Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ gba inú funfun wa kúrò ó sì sọ wá di aláìmọ́. Nítorí Ó jẹ́ mímọ́ àti pípé, Ọlọ́run ò lè ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ohunkóhun tó ní àìmọ́. Ìpínyà yí ba Ọlọ́run nínú jẹ́ nítorí Ó fẹ́ràn wa ju bí a ti lérò lọ. Lọ́gán ni Ọlọ́run ṣètò ìmúbọ̀sípò wa pẹ̀lú ara rẹ̀. Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dálé àwa ènìyàn, a ti ṣe ìpinnu rẹ̀ wípé Jésù yóò jẹ́ alábápín nínú ìtàn náà.

Ọlọ́run fi yé Sátánì lọ́jọ́ náà irú ìdájọ́ tí ń dúró dè é. Ó sọ wípé, “N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Bí ìtàn náà ti ń lọ ni a ti rí, láàárín àwọn ọmọ Eéfà, Olùgbàlà kan tí yóò já agbára Sátánì láti fa ìdàrúdàpọ̀ láàárín Ọlọ́run àti ènìyàn gbà títí láíláí. Sátánì ma gbìyànjú láti mú ìdíwọ́ wá, àmọ́ Olùgbàlà náà yóò fọ́ oríi rẹ̀. Kò sí bí yóò ti gbérí mọ́ lẹ́yìn èyí!

Kérésìmesì sààmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ètò Ọlọ́run láti ṣe ìmúbọ̀sípò ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú ara Rẹ̀ nípasẹ̀ Májẹ̀mú titun. Gbogbo àgbáyé ló dúró fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún fún Olùgbàlà tí Ọlọ́run ṣèlérí, ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín rẹ̀, Ó ti wá dé báyìí. Ẹni náà tí yóò borí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú láíláí ti wá di 'Ọlọ́run pẹ̀lú wa.'

Bí a ti ń wọ àkókò Ìbí Jésù yí, fi ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run ìṣáájú nà ṣe àfojúsùn rẹ. Mọ̀ dájú wípé ẹsẹ̀ Ọlọ́run kìí yẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, kí o sì máa ṣe àṣàrò nínú òtítọ́ wípé Ó fẹ́ràn rẹ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó rán Ọmọ Rẹ̀ aláìlàbàwọ́n wá sí ayé ẹ̀ṣẹ̀ yí kí Ó ba lè ní ìbárẹ́ pẹ̀lú rẹ.

Àdúrà: Baba, ẹnu yà mí nígbà tí a fi yé mi wípé èsì Yín àkọ́kọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́ ìlérí wípé kì yóò jẹ́ ìdíwọ́ fún ìbárẹ́ wa láíláí. O Ṣeun fún bí o ti yan Jésù láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ láti lànà ìbáṣepọ̀ láàárín àwa àti Ìwọ. Bí a ti ń gbẹ́nu lé Kérésìmesì lọ́dún yìí, fún mi ní ìṣípayá tó jinlẹ̀ nípa ǹkan tí O gbé ṣe nípasẹ̀ Jésù tó wá sáyé. Jẹ́ kí n lè ní ìrírí ayọ̀ tó dé bá Ọ nígbà tí a bí Jésù àti nígbà tí àṣekágbá mímú ìlérí náà ṣe bẹ̀rẹ̀.

Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán t'òní ní bí

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/