Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Bíbẹ̀rẹ̀ Ní Ipele Kékeré
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù jẹ́ ìlú kékeré, èyí tí kò lókìkí bíi àwọn ìlú ńlá tó wà ní àyíká rẹ̀. Nínú ògbùfọ̀ Bíbélì ní ẹ̀yà MSG fún Míkà 5:2, a ṣe àpèjúwe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù gẹ́gẹ́bí “wòròmọ-dìyẹ láàrín àṣá.” Kí ló mú kí Ọlọ́run gba irú ìlú tí kò lórúkọ yìí wá sáyé? Ǹjẹ́ ó yẹ ní ìlú tí a lè bí Ọba àwọn Ọba sí?
Ǹkan tó wá ṣẹlẹ̀ ni wípé, Ọlọ́run kò fìgbà kankan ka gbèdéke àwọn ènìyàn nípa òkìkí sí. Ọrọ̀, òkìkí, gbajúmọ̀, agbára—kò sí ìkankan nínú gbogbo rẹ̀ tí Ọlọ́run kà sí. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì, “Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára.” Ǹkan tí ó lè gbé ṣe ní ayé ẹnìkan kò pin sórí gbèdéke tí a gbé wọ́n sí ní ayé yìí. Tí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù bá wá jẹ́ “wòròmọ-dìyẹ,” báwo ni ògo Ọlọ́run yóò ti nìyí tó tí ó bá fi ìpìlẹ̀ Ọmọ Rẹ̀ lélẹ̀ síbẹ̀? Ibi tí ìrìn-àjò Jésù ti bẹ̀rẹ̀ kò dífá fún ohun tó lè gbé ṣe nínú Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kìí ṣe bí ọ̀rọ̀ àwa náà ti rí nìyí?
Àdúrà: Baba, ẹ ṣeun tí ẹ kò jẹ́ kí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ayé mi jẹ́ òṣùwọ̀n ipele tí mo lè dé. Ẹ ṣeun tí ẹ fi ìwúlò àtọ̀runwá fún aláìmọ̀ọ́ṣe bíi tèmi. Mo fi ìyìn fún Ọ nítorí agbára Rẹ iyebíye tó ń gbé mi ró ní àkókò ìrẹ̀wẹ̀sì. Mo mọ̀ wípé ibikíbi tí mo lè ti bẹ̀rẹ̀, O ma mú mi dé ibi tí ò ń mú mi lọ. O ṣeun, Jésù, tí o fi hàn sí mi wípé àwọn ǹkan àrí-kọ-hà a máa bẹ̀rẹ̀ láti ibi kéréje.
Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán tòní níbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More