Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 6 nínú 25

Ọba Tó Ju Gbogbo Ọba Lọ 

Orin Dáfídì 72 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà Ọba Dáfídì fún ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì, láti di ọba olókìkí ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Bí orin yìí ti ń tẹ̀síwájú, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí ní ronú nípa Ọba pípé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjọba Jésù. Ní ọdún 950-ó-lé kí a tó bí Jésù, Dáfídì rí ìjọba àìlópin ti Ọba àwọn Ọba. A óò mọ Ọba yìí fún ìkannú rẹ̀ àti ìgbàlà tí yóò ṣe fún àwọn aláìní àti àwọn tí ń jẹ̀róra. Yóò boríi jàgídí-jàgan àti ìmúnisìn, yóò sì wá hàn gbangba wípé àwọn ènìyàn Rẹ̀ ṣe iyebíye sí I. Fún àwọn ìdí wọ̀nyí, Dáfídì kéde rẹ̀ wípé gbogbo àwọn ọba ní yóò wólẹ̀ Fún-un àti wípé àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo ni yóò sìn Ín.

Dáfídì mọ wípé ṣíṣe àánú àti ìtọ́jú àwọn ènìyàn Ọlọ́run, pẹ̀lú jíja ìjàkadì àti bíborí ìmúnisìn, ní àwọn àmì Ọba tó pé—èyí tí ìdájọ́ ìhùwàsí àti àìmọtaraẹninìkan rẹ̀ kì yóò mẹ́hẹ láíláí. Ní àfikún sí wípé ó jẹ́ àkókò tí a bí Olùgbàlà sáyé, Kérésìmesì sààmì sí ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Ọba tí ó tóbi jù ní ayérayé ṣe. Jésù yóò sì máa jọba lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọba àti ìjọba bá ti ré kọjá, tí a ó sì ní àǹfààní láti gbé lábẹ́ ìbòjí ìfẹ́ Rẹ̀ pípé títí láé.

Àdúrà: Jésù, Mo bọ̀wọ̀ fún Ọ gẹ́gẹ́bí Ọba lórí ayéè mi ní ayé yìí àti fún ayérayé! Pẹ̀lú ìnọ̀gà ni mo fi ń retí ìdarí rẹ bí ayé yìí ti ń ṣègbé lọ. O ṣeun tí o wá sáyé tí o sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ lọ sí orí ìtẹ́ láàárín wa. Mo dúpẹ́ lọpọlọpọ fún bí o ti tọ́jú mi àti bí ẹ ó ti máa gbèjà mi gẹ́gẹ́bí Ọba. Mo fẹ́ràn Rẹ mo sì jọ̀wọ́ ara mi láti tẹ̀lé ọ̀nà Rẹ pípé.

Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán tòní níbí

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/