Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ

Advent: The Journey to Christmas

Ọjọ́ 11 nínú 25

Kíni Ó Wà ní Òdì-kejì “Bẹ́ẹ̀ni” Rẹ?

Màríà múu dàbí ohun tí ó rọrùn. Áńgẹ́lì Gebureli sọ fún-un wípé yóò bí Ọmọ Ọlọ́run, lọ́gán ló sì ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. Kíni ó ń la ọkàn Màríà kọjá lákòókò náà? Kòní ìdánilójú àbájáde tó rọrùn. Wúńdíá tí a ti fi m'ọkọ tó sì ń dúró láti ṣe ìgbéyàwó niíṣe, ó ṣeé ṣe kó mọ bí ìbí àti títọ́ Jésù yóò ti nira tó. Ìpẹ̀tù kan tí Màríà rí gbà ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ ìwúrí tótó fún-un láti sọ wípé “bẹ́ẹ̀ni.”

Nínú Pétérù Kínní 1, àpọ́sítélì Pétérù sọ wípé nípasẹ̀ ìdojúkọ tí à ń ní, ni a fi lè mọ bí ìgbàgbọ́ wa ti jẹ́ ojúlówó sí. Ọlọ́run ń retí ìjẹ́rì wa nínú àwọn ìlàkọjá tó le, tó nira, àti èyí tó dàbí wípé kò ṣeé ṣe. Àmọ́ njẹ́ àwa tilẹ̀ ma ń dáhùn bíi Màríà bí? Ó ṣeé ṣe kí pípe-Ọlọ́run-níjà ṣe ìdíwọ́ fún ǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe nínú tàbí nípasẹ̀ wá. A lè fẹ́ ní ìsọdọ̀tun, àmọ́ ṣé a ṣetán láti ṣe “bẹ́ẹ̀ni” sí Ọlọ́run kí a sì la iná kọjá?

Ó dánilójú wípé Màríà kò mọ ohun tí yóò tẹ̀yìn èsì rẹ̀ sí Ọlọ́run yọ, àmọ́ ó ní ìjẹ́rì nínú Rẹ̀. Fún ìdí èyí, Ọlọ́run mú Jésù wá sí ayé nípasẹ̀ Màríà, ó sì fúnwa ní àǹfààní ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àtúntò ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run tó ti mẹ́hẹ.

Ní àkókò Kérésìmesì yí, ṣe àgbéyèwò èsì Màríà sí ètò Ọlọ́run nípa ìbí Jésù. Kíni iṣẹ́ tó ń peni níjà tí Ọlọ́run ti fi sí oókan àyà rẹ? Bóyá mímú ìbáṣepọ̀ tó ti mẹ́hẹ bọ̀sípò ni tàbí gbígbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ètò Rẹ̀ fún ọ, mọ́kànle pẹ̀lú ìdánilójú wípé ní òdì-kejì “bẹ́ẹ̀ni” tí o ṣe sí Ọlọ́run ni àbájáde tó tóbi ju bí o ti lérò lọ gbé wà.

Àdúrà: Baba, mo ní ìdánilójú wípé ìfẹ́ Rẹ jẹ́ pípé. Mo gbàdúrà pé Ìwọ yóò fi ìfẹ́ Rẹ sí oókan àyà mi, kí O sì jẹ́ kí ìfẹ́ mi wà ní ìbámu pẹ̀lú Tìrẹ. Mo dúpẹ́ fún àpẹẹrẹ to fún mi nínú Màríà. Jọ̀wọ́ fún mi ní ọgbọ̀n, ìgboyà, àti ìgbàgbọ́ tí mo nílò láti ṣe “bẹ́ẹ̀ni” sí ètò Rẹ fún ayée mi.

Ṣe àkáálẹ̀ àwòrán tòní níbí . 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 10Ọjọ́ 12

Nípa Ìpèsè yìí

Advent: The Journey to Christmas

Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.

More

A fé láti dúpe lówó Church of the Highlands fún ìpèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i,E jòó ṣèbẹ̀wò:https://www.churchofthehighlands.com/