Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Olórun tó n se ohun kò seé se
Ní Lúùkù 1:34, lèyín tí ángèlì sò fún Màríà pé yóò bí Jésù,ó béèrè lówó rè, “ Báwo ní èyí máa see se, nítorí wúndíá ní mi?” Màríà se ohun tá sábà máa ń see nígbà tí a kò bá rí bi ohun máa se ṣiṣẹ́ yọrí. Ó béèrè bí nñkan kan tó dá bí pé kò seé se lè seé se.
Àmó àngélì náà dá a lohùn, “ Èmí Mímó yóò wá sórí rè, àti agbára Ènì Gíga Jù Lọ má ṣíji bò ọ́; àtipe fún ìdí èyí à yóò pè Omo Mímó náà ní Omo Olórun. Àtipe kíyèsíi, kódà mọ̀lẹ́bí rè Elisabẹti tí lóyún Omokùnrin kan náà ni ojó ògbo rè; àtipe wón pè ni àgàn lówólówó báyìí tí wá ni osù kefà rè. Nítorí kò sí ohun tó má sòrò pèlú Olórun.”
Kódà ni àkókò tó rewà bí Kérésìmesì, o lè sòrò láti rí bí Olórun ń se sisé ni àwon ipò wa tó sòrò. Lónìí, jé kí àwon isé ìyanu méjèèjì tí ìllóyún ràn è létí nípa agbára Olórun. Ronú nípa Jésù àti omo Elisabẹti, Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àti bí àwon ìbí wón se sàyípadà ipa-ònà ìtàn. Olórun lè se ohun aláìṣeédíwọ̀n ju bí ó tí lè finú wòye lo láàárín ìsòro rè. Gbé ipò rè fún Un, àti gbékèlé pé Yóò jé olódodo. Níṣìírí lónìí: Olórun Kò lè kùnà láé!
Àdúrà: Bàbá, E dára! Mo yìn Yín fún agbára Yín—kò sí ohun tó lè dúró lòdì sí Yín! E se pé E ní ètò fún ayé mi,fún rírán Omo Yín nítorí témí àti fún fifún mi lókun láti kojú àwon ipò ìsòro. Bí mo ń ṣẹ gbékèlé òkun Yín láìse tèmí, E ràn mi lówó láti rí Kérésìmesì gégé bí àpẹẹrẹ alágbára pé kò sohun to sòrò fún Yín.!
Gbà àwòrán tónìí jáde níbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More