Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Olórun kò Jìnnà
Nínú àlá Jósẹ́fù, àngélì náà fi hàn pé ìbí Jésù yóò se ìmuse àsọtẹ́lẹ̀-òrúdún ògbo àtipe fi òpin sí ìpínyà tó wá sáyé láàárín Olórun àti ènìyàn àti èsè akókó ní ọgbà Édẹ́nì. Jósẹ́fù mò pé Jésù yóò jé “Olórun pèlú wa.” bí o se rọrùn láti gbàgbé òtítọ́ yìí!
À kà nínú Ẹ́kísódù, pé kí ìbí jésù tó sèlè, pé Mósè ní láti dúró de Olórun láti sòrò fún un lórí òkè tàbí nípasè igbó tó ń jó. Ní àkókò náà, aráyé kò ní àjose tímọ́tímọ́ lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo pèlú Olórun. Nígbà mìíràn, o lè rorùn fún wa láti yọ́ wọnú èrò orí ogbó yìí nípa bibá Olórun sòrò. Báwo ní a sábà máa ń béèrè síbè fún igbó tó ń jó tí ara wa,áti ń fé àmì, tó fi hàn kedere gbòógì tàbí òrò tó dájú láti òdò Rè? Kódà gégé bí Kristeni, à lè bèrè sí ní gbàgbó pé Olórun jìnnà nígbà tí a bá ń dúró àti ń dúró láti gbó láti òdò Rè.
A ní láti ràntí pé Jésù tí fi afárá si àlàfo láàárín awa àti Olórun. Òun ní ìdáhùn Olórun sí ifé okàn wa fún igbó tó ń jó tàbí ìjíròrò orí òkè pèlú Rè. À kò se ìjosìn Olórun tó jìnnà réré tí kò fé sòrò sí wa. Jésù tí mú ìbáṣepò padà bọ̀sípò pèlú Rè àti mú ònà fún wa láti sún mó Ìté Rè pèlú ìgboyà lójoojúmó.
Ní Kérésìmesì èyí, wá ìtùnú ní mímò pé Olórun wá pèlú rè. Ó gbó àwon àdúrà rè, àti Ó wa fún è. Ti Olórun bá lè yanjú ìbáṣepò wa tó túká pèlú Rè, rònu àwon ohun tí Ó lè àtipe máa se ní ayé wa àti nítorí wa!
Àdúrà: Bàbá, E seun fún èbùn Yín tí Jésù, pé Ó se ònà fún mi láti sún mó Yín lẹ́ẹ̀kan sí i. E seun fún fifé ìbáṣepò pèlú mi gidigidi gan-an pé E rán Omo Yín Kan soso láti kú ní ipò mi. Bàbá, È fún mi ni ìgboyà láti wá A nínú àdúrà àti ìjosìn, ní mímò pé mo ní lárọ̀ọ́wọ́tó si Yín lẹ́ẹ̀kan sí nípasè Jésù. È seun fún fifún mi ní ìdánilójú pé È wà nígbà gbogbo pèlú mi, pé mi kò dá wà nìkan láé.
Gbà àwòrán tónìí jáde níbí.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More