Bíbọ̀wá: Ìrìn Àjò Sí KérésìmesìÀpẹrẹ
Ìràpadà Fún Ìrètí Ìgbà Gígùn
Bóyá ó tí gbó òwe, “Ìrètí pipè má n mú okàn sàìsàn.” sùgbón se o mò pé a bí Jésù nítorí Olórun rà ìretí ìgbà pipè padà? Ní Jẹ́nẹ́sísì, a ká pé Ábúráhámù àti ìyàwó rè Sárà yánhànhàn fún omo fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, sùgbón Sárà yàgàn. Nígbà tí Sárà jé àádọ́rùn-ún ọdún, Olórun fara hàn sí Ábúráhámù àtipe sellérí pé Sárà yóò bí omo okùnrin kan, àtipe nípasè omo náà, Yóò fìdí májẹ̀mú ayérayé múlẹ̀ láàárín Rè àti àwon àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Sárà pàápàá rérín nígbà tí Olórun so èyí, nítorí ó ronú, “báwo ní obìnrin gbígbó bí èmi má se gbádùn irú ìtẹ́lọ́rùn yen?" Síbè Sárà lóyún àtipe bí omo kan. Ábúráhámù so lórúko “Ísáákì,” tó túmò sí “èrín,” nítorí Olórun mú ìdùnnú nlá wá fún Sárà àti ìràpadà nípasè ohun tó sèlè tó dà bíi ipò to ìsòro.
Omo Ísáákì ni Jékọ́bù, Jékọ́bù ní omo okùnrin méjìlá, oókan tó jé Júdà. Lára àwon èyà Júdà ní Oba Dáfídì tí wá, àtipe nítorí ìya’ Jésù Màríà jé àtọmọdọ́mọ Dáfídì (gégé bí Jósẹ́fù bàbá Rè tayé náà), Olùgbàlà dí èso ìllérí Olórun sí Ábúráhámù àti Sárà. Bí Olórun se wò ara Sárà sàn àtipe se ìmúse ifé okàn rè, Ó gbin irúgbìn kan tó má rà èdá ènìyàn padà sí Ara Rè nígbẹ̀yìngbẹ́yín, n fìdí májẹ̀mú múlè tó má pé títí ayérayé. Agbára Sárà láti bímo ní ojó ogbó è fún wa ní ìdí mìíràn láti wa ni awe tí itàn ìyanu ìbí Jésù
Tí ó bá n kojú ìrètí ojó pipè lónìí,fokàn balè pé Olórun ní ìràpadà fún àsìkò àtipe Yóò mú nípa ìpadà nlá tó ju bí ó se lè fojú inú wò lo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kò lè rí ète nínú rè báyìí, lojó kan, yóò rí. Dí àwon ìllérí Olórun mú! Bí Sárà, ó má nírìírí pé, “ìmúse pipè igi ìyè ni.”
Àdúrà: Bàbá, È ṣeun fún jijé Olórun òrò Yín. Gégé bí È se semúse ìllérí Yín si Sárà, Mo gbékèlé pé È má se semúse àwon ìllérí Yín si mi. Mo dúpé lówó Yín sáájú fún ìlò àwon àkókò ìsòro nínú ayé mi fún ète nlá. Olá jé tèmi láti jé ara isé tó fógo fún Yín.
Gbà àwòrán tónìí jáde nibi.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ èyí tó ní ọlá jùlọ lóòótọ́: èyí tó dá lóríi ìṣòótọ́ Ọlọ́run, agbára, ìgbàlà, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. Jẹ́ kí a lọ lórí ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ńgbọ̀n láti ṣe àwárí ètò pípé Ọlọ́run láti gba ayé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ìlérí tí a mú wá sí ìmúṣẹ nípa ìbí Ọmọ Rẹ̀.
More