Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ
Bíbélì Wá Láàyè
Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wa. Ó jẹ́ àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run làti ipa'sè ènìyàn lórí ìṣesí Rẹ̀, àti àwọn ìpinnu Rẹ̀ láti gba àwọn ẹ̀dá ènìyàn àti láti mú wọn bọ̀ sípò. Bí a ti wá t'ọwọ́ Ọlọ́run gbé e kalẹ̀ nípa ìmísí, gbogbo abala Ìwé Mímọ́ ló ní agbára láti gbani nímọ̀ràn, gúnni lọ́kàn, ati láti yíni padà.
Ronú àkókò kan tí ó hàn sí ọ dájú wípé ìsọdọ̀tun ń débá ọkàn rẹ, tàbí tí o rí àwọn àyípadà ní àwọn agbọndan ayé rẹ kan. Tí o bá ń ka, tàbí gbọ́, Ìwé Mímọ́ déédé, o ti ní ìrírí agbára rẹ̀ láti fúnni ni ìṣípayá, ìgbani-níyànjú àti láti pèọníjà.
Bíbélì ju ẹ̀kọ́ nípa ìtàn àdáyébá. Bótilẹ̀pé óun sọ ìtàn nípa àwọn ǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe, o tún ń ṣe àfihàn òun tí Ọlọ́run yóò ṣe. Òun ṣe àfihàn ìtàn ti Ọlọ́run ti ń sí ìbòjú rẹ̀, láwẹ́ láwẹ́, láti àtètèkọ́ṣe; ìtàn tí Ó fẹ́ tesiwaju láti máa sọ nípasẹ̀ wa.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti la ọkàn àwọn ènìyàn kọjá láti ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo, ìmísí tó mú wá sì ti yọrí sí àyípadà ìlú, orílẹ̀-èdè, àti kontinenti.
Nítorí náà ní ọ̀sẹ̀ yí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ bí Bíbélì ṣe wà láàyè àti bí ó ti ń ṣ'iṣẹ́ nínú ayé wa nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìtàn tí Ọlọ́run ti ń sọ nipasẹ̀ àwọn Kristẹni láti àtètèkọ́ṣe—ìtàn tó ńṣe àfihàn agbára Bíbélì láti la òkùnkùn kọjá, lati mu ìrètí wá, láti mú ayé ènìyàn padà bọ̀sípò, ati lati yí gbogbo àgbáyé padà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.
More