Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ
Bíbélì ńyí ohun gbogbo padà
Ìwọ wo bí ohun gbogbo se sókùnkùn biribiri, tí ó sì rí júujùu kí Ọlọ́run tó mí ọ̀rọ̀ rẹ̀, óní kí "Ìmọ́lẹ̀ wà". Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun gbogbo yí padà. Ìmọ́lẹ̀ yí bo òkùnkùn biribiri, a sì rí àwọn ohun tí a kòrí tẹ́lẹ̀ ní kedere. Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Olọ́run yí ohun gbogbo padà - sùgbọ́n kò pin síbẹ̀
Olọ́run tí ó dá gbogbo àgbáyé pèlú èémí kan ńtẹ̀síwájú ó ńmí ìgbé ayé titun sínú ayé nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Olọ́run ńtẹ̀síwájú láti bo òkùnkùn mọ́lẹ̀. Ọ̀rọ̀ Olọ́run ńyí ìgbésí ayé padà, ó sì ńsọ awọn ọkàn tí ó wà ní ìpòrurù di ọ̀tun. Ọ̀rọ̀ Olọ́run wà lààyè ósì ńsisẹ́ lọ́wọ́ nítoríỌlọ́run wà láàyè ósì ńsisẹ́ lọ́wọ́. A sì ní àyè sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo.
Bí a se ńka Bíbélì si, bẹ́ẹ̀ni a ó se rí pé Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé ní ìrírí ọ̀kọ̀ọ̀kan, tí yó ní àtúnse nínú ayé wọn pẹ̀lú rẹ̀.
Kò sí irú ìpọ́njú tàbí wàhálà tí dojú kó wa, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò tẹ̀síwájú láti má borí òkùnkùn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò tẹ̀síwájú láti má yí àwọn ènìyàn bíi Ghana, Sumu, àwọn ènìyàn Popoluca, Samuel Àjàyí Crowther, àti William Tynale padà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ní agbára láti yí ọ padà.
Nítorínáà, dúró kí o ro nípa ìtàn rẹ. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run se sọ ẹ́ dọ̀tun? Àti irú ọ̀nà wo ni Ọlọ́run se mú kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà láàyè nínú ayé rẹ nísìsiyì?
Se àjọyọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ti se nínú ayé rẹ di ìgbàyí, kí o sì se àyẹ̀wò lórí ohun tí Ó ńse nínú ayé, pàápàá ní àyíká rẹ.
Síwájú sí, yan láti kópa nínú ìtàn tí Ọlọ́run ńsọ. Ójẹ́ ìtàn tí ó bẹ̀rẹ̀ nígbàtí Ó sọ Ọ̀rọ̀ tí ayé sì wà, yóò sì tẹ̀síwájú títí ọjọ́ ìpadà bọ̀ Jésù - ìtàn tí ó síwájú ìtàn, tí ó sì ńtẹ̀síwájú tí ó ńsọ gbogbo ayé dí ọ̀tun
Nípa Ìpèsè yìí
Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.
More