Bíbélì Wà LáàyèÀpẹrẹ

كلمة الله حية

Ọjọ́ 3 nínú 7

The Bíbélì Ń Yí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Padà

Ní àwọn ọdún ẹgbẹ̀rún méjì din ni igba. Ọmọ ọdún méjìlá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kan àti ìdílé rẹ̀ ni wọ́n fi ipá mu bi ẹrú wo ọkọ̀-ojú-omi ilẹ̀ Portugal tí ń kẹ́rù lọ sí Amẹ́ríkà. Ṣùgbọ́n kí ọkọ̀ ojú omi yìí tó gbéra kúrò ní èbúté agbègbè Áfríkà, ó ṣe alábapàdé àwọn ikọ̀ to n gbé ìjà kọ àwọn olókowò ẹrú ti wọn si mú wọn. Ọ̀dọ́mọ-kùnrin yìí àti ìdílé rẹ̀ ni wọn dásílẹ̀ tí wọ́n sì fi wọ́n ṣọwọ́ sí ìlúu Sierra Leone. Ní ìlú yìí ni ó ti ní ìṣínilójú nípa agbára Bíbélì. 

Lẹ́yìn tí ó di Kristẹni, Samuel Ajayi Crowther bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ èdè oríṣiríṣi, o sì tun ma ń lọ ìrìn àjò láti jí ìhìn rere, ìyẹn ní àwọn ìlú tó yi ilẹ̀ Sierra Leone ká. Ni gbogbo àkókò yí, ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nítorí pé ko ti si ẹ̀dà Yorùbá—èdè abínibí rẹ ní Nàìjíríà. 

Èyí túmọ̀ sí pé, àwọn tí kò sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìlú Nàìjíríà kò lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra wọn. Fún ìdí èyí, Àjàyí ṣe ètò ìlànà gírámà láti ka èdè Yorùbá, lẹ́yìn náà ó wá túmọ̀ Bíbélì sí èdè náà. 

Ní kété tí o parí ẹ̀dà Bíbélì ní Yorùbá ó tẹ síwájú láti ma túmọ̀ Ìwé Mímọ́ si àwọn èdè míràn ní Nàìjíríà kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn náà lè ṣe alábapàdé ìrírí tí ó nyí ayé ẹni padà tí òun náà tí ní. 

Àwọn ìjọ Anglican yan Crowther ní “Bísọọbù ti Niger” èyítí ó sọọ́ di àkọ́kọ́ irú-ọmọ adúláwọ̀ Bisọọbu Anglican. Lónìí, àkójọpọ̀ ìjọ Anglican tí ilẹ̀ Nàìjíríà ni o tóbi ṣìkejì pẹ̀lú mílíọ̀nù méjìdínlógún ọmọ lẹ́yìn tí a ti ṣe ìtẹ̀bọmi fún. 

Ọlọ́run yí kan náà Tó ṣíṣe nínú Crowther Ó fẹ́ ṣíṣe ba kan náà làti rẹ láti fi ipasẹ̀ rẹ sínú ayé nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ló ń pòǹgbẹ fún àyípadà nípasẹ̀ Bíbélì, àwọn tó jẹ́ pé ìwọ nìkan ní ó ní àǹfààní làti kàn sí wọn.

Nítorínáà lónìí, bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àfihàn ipa tí o le ko nínú ìtàn tí Ọlọ́run nsọ, kí ó sì máa wòye bí yóò ti ṣe àmúlò ayé rẹ síwájú si ju bí o ti le béèrè, rò, tàbí dá ní àbá.  

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

كلمة الله حية

Ní àtètèkọ́ṣe, ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń mú ọkàn àti ẹ̀mí àwọn ènìyàn bọ̀sípò—Ọlọ́run ò sì tíì parí iṣẹ́. Nínú Ètò pàtàkì ọlọ́jọ́-méje yìí, ẹ jẹ́ kí a ṣe àjọyọ̀ agbára Ìwé Mímọ́ tó ń yí ìgbé-ayé ẹni padà nípasẹ̀ ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà lo Bíbélì láti yí àkọsílẹ̀-ìtàn padà àti láti mú àyípadà dé bá ìgbésí ayé àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.