EbiÀpẹrẹ
Ebi gẹ́gẹ́ bí Òté fún púpọ̀ si
Ebi máa ń pa onírúurú àwọn ènìyàn ní onírúurú àsìkò nínú ọjọ́. Àwọn ènìyàn kan máa ń jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mẹta lójúmọ́. Àwọn kan máa ń ṣe àhejẹ ní ààrin. Ebí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìṣe ojóojúmọ́ ènìyàn. Gbogbo wa nílò láti jẹun. Òtítọ́ sì ni pé ebi ti ara máa ń ṣàpẹẹrẹ ìjìnlẹ̀ òtítọ́ ẹ̀mí: a ṣètò wa láti pòǹgbẹ Ọlọ́run.
À ń gbé ìgbésí-ayé Kristẹni nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu, nítorí náà ó ní í ṣe pẹ̀lú kí á máa ṣe déédéé, dàgbà si nínú òùngbẹ wa fún Un sí I àti láti gbé nínú ìwàláàyè Rẹ̀. Jesu sọ pé àwọn tí ó ní ebi àti òǹgbẹ fún òdodo yóò di ẹni ìbùkún nítorí ti wọn yóò yó. Bóyá ìwọ pẹ̀lú mọ ebi rẹ nipa ti ẹ̀mí. Bóyá àwọn apá kan wà tí ó nílò kíkún pẹ̀lú òdodo Ọlọ́run.
Nígbà tí Jesu wá sí ayé yìí, ó tọ́ka àwọn ènìyàn padà sí èrèdí Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ní ti ìdàpọ̀-míma òtítọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ àwọn ènìyàn tí ebi wọn fún Un àti Ìjọba Rẹ̀ ju ohungbogbo lọ. Jesu ṣe àpẹẹrẹ òtítọ́ yìí nígbà tí ó sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé oúnjẹ òun ni láti ṣe ìfẹ́ Baba, àti pé ẹnikẹ́ni tí òǹgbẹ bá ń gbẹ lè wá sí ọ̀dọ̀ Òun láti mu lọ́fẹ̀ẹ́ nínú odò omi ìyè.
Ebi fún Ọlọ́run – ìfẹ́ yìí láti wá sínú ìrírí ẹlẹ́wà láti mọ̀ Ọ́n – ti jẹ́ òté tó wọ́pọ̀ èyí tó ń so àwọn ènìyàn Ọlọ́run pọ̀ láti ìrandíran. Mímọ̀ Ọ́n máa ń ta wá nídìí lọ sínú àwọn èrèdí Rẹ̀ fún ayé wa. Mímọ̀ Ọ́n túmọ̀ sí pé a máa wà lára Ìjọba Rẹ̀, títẹ̀síwájú nínú dídára rẹ̀, káàkiri àgbáyé.
Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́ mọ̀ pé ìgbésí-ayé ní orí-èèpẹ̀ kò níye pups lórí àfi bí wọ́n bá ń farajìn pátápátá fún gbígbé ayé fún Ọlọ́run. Paulu kọ̀wé rẹ̀ pé ìfẹ́ Kristi kàn án nípá fún wa láti máṣe gbé ayé fún ara wa ṣùgbọ́n fún ẹni tí ó kú fún wa. Ayé tí kò bá pòǹgbẹ Ọlọ́run wà nínú ewu gbígbé ayé ara ẹni àti àwọn ohun òfo inú ayé yìí. Irú ayé bẹ́ẹ̀ kò lè kópa nínú ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run èyí tí ó ń fi wá sípò tó sì ń fi agbára fún wa láti fi Ìjọba Rẹ̀ lọ́lẹ̀ ní ayé.
Bí a ṣe ń pòǹgbẹ Ọlọ́run síwájú sí i, a máa rí i pé kò sí òpin nínú mímọ̀ Ọ́n. Fi àsìkò díẹ̀ ṣe ìgbéléwọ̀n ìpòǹgbẹ rẹ. Kí Ọlọ́run fi kún ìfẹ́ rẹ láti mọ̀ Ọ́n, sọ Ọ́ di mímọ̀, àti láti dásẹ̀ wọ inú àwọn ètò àti èrèdí rẹ̀ fún ayé rẹ. kí ó mú ìmọ̀ rẹ kún sí i débi pé kò sí ohun ti ayé yìí tí yóò tẹ́ ọ lọ́rùn. Kí o sì dù láti gbélé ayé fún Jesu nìkan.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà kíkà yìí ṣe àwàjinlẹ̀ bí ebi wa láti mọ Ọlọ́run kí á sì sọ ọ́ di mímọ̀ máa ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ sínú èrèdí rẹ̀ fún ayé wa. Ṣe àwárí ohun tí ó sọ Dafidi di ẹni bí ọkàn Ọlọ́run – àti bí ìwọ pẹ̀lú ṣe lè gbé ayé pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn-kan fún Ọlọ́run, gbígbádùn ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jesu àti gbígbẹ́kẹ̀le láti tẹ́ àìní rẹ larùn.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Lawrence Oyor fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.youtube.com/lawrenceoyor