EbiÀpẹrẹ
Ebí nínú Ayé Ìṣubú
Bóyá o lá àlá jíjẹ tẹ́tẹ́ kan tàbí jíjogún owó tabua kan. Ó ti pinnu ohun tí wàá fi àwọn owó náà ṣe. lóòótọ́ ni pé gbogbo ẹ̀bùn pípé àti dídára ń ti ọwọ́ Ọlọ́run wá, Òun sì ni olùpèsè wa níti ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n a pè wá sí ohun tí ó pọ̀ tayọ lílé ọrọ̀ ayé tàbí àwọn ìtẹ́lọ́rùn ayé. Bàbá rẹ ọ̀run tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ fẹ́ kí o mọ̀ nipa àwọn ewu tó wà nínú pípòǹgbẹ fún àwọn nǹkan tí ayé ń fún ni, àti àlàáfíà iyebíye tí wà á ní ìrírí nígbà tí o bá pòǹgbẹ Jesu ṣáájú ohun gbogbo.
Jesu ṣe àkíyèí pé àwọn ènìyàn kan ń bu ọlá fún Un pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí Òun. Ó bani lọ́kàn jẹ́ pé èyí jẹ́ òtítọ́ fún ìjọ ní ìran yìí, èyí tí àwọn èrò ayé ti nipa lórí rẹ̀ gan-an. Kì í ṣe ohun tí kò wọ́pọ̀ láti rí àwọn Kristeni tí wọ́n ń pòǹgbẹ fún ọrọ̀ àti ìrọ̀rùn ayé ju bí wọ́n ṣe ń pòǹgbẹ Jesu lọ. nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti bèèrè lọ́wọ́ ara wa bóyá à ń wá Ọlọ́run fún èrè ẹran-ara nìkan (gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti rí ohun à ń wá), tàbí bóyá à ń lépa ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ nítorí pé ọkàn wa pòǹgbẹ láti mọ̀ Ọ́n sí i.
Jesu ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé àwọn aláìgbàgbọ́ (ní àsìkò Tirẹ̀, àwọn Kèfèrí) máa ń lépa ohun tí wọn ó jẹ, mu àti wọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́gán tí àwọn ènìyàn bá ti gba àwọn nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Ọlọ́run, olùpèsè wọn, iná ẹ̀mí wọn á kú. Ó ṣe é ṣe kí o ti rí àníyàn àti wọ̀bìà tí ó ń dípò ebi tòótọ́ fún Ọlọ́run, nínú ìjọ tàbí àwùjọ rẹ lápapọ̀. Ó ṣe é ṣe kí ó ní ìmọ̀ tó ń dàgbà sókè sí i nipa pé ìwọ àti àwọn onígbàgbọ́ bíì rẹ ni a pè láti ṣe àfihàn ìgbésí-ayé aláìnáání-ohun-ayé fún ayé.
Ìwàásù Jésù kò fi ìgbà kan ṣe ìgbélárugẹ fún irúfẹ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tàbí wọ̀bìà ohun ìní ayé tí ó wà lákàtà wa lónìí, nítorí náà a kò gbọdọ̀ so títẹ̀lé E mọ́ àwọn èrè ayé. Kò sí ohunkóhun ní ayé tí ó ṣe pàtàkì bí i mímọ̀ àti ṣíṣe Ọlọ́run logo. Ẹ jẹ́ ká farajìn fún dídarí àwọn ìfẹ́ was í wíwá A lákọ̀ọ́kọ́ – ju ohun gbogbo lọ - àti láìsí ìrètí òdì fún èrè yàtọ̀ sí ayọ̀ mímọ̀ ọ́n àti sísọ Ọ́ di mímọ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà kíkà yìí ṣe àwàjinlẹ̀ bí ebi wa láti mọ Ọlọ́run kí á sì sọ ọ́ di mímọ̀ máa ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ sínú èrèdí rẹ̀ fún ayé wa. Ṣe àwárí ohun tí ó sọ Dafidi di ẹni bí ọkàn Ọlọ́run – àti bí ìwọ pẹ̀lú ṣe lè gbé ayé pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn-kan fún Ọlọ́run, gbígbádùn ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jesu àti gbígbẹ́kẹ̀le láti tẹ́ àìní rẹ larùn.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Lawrence Oyor fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.youtube.com/lawrenceoyor