EbiÀpẹrẹ

Ebi

Ọjọ́ 2 nínú 4

Ebí jẹ́ Ẹ̀jẹ̀-Ìran (DNA) Dafidi

Fún dídára tàbí àìdára, o fi àwọn nǹkankan jọ àwọn òbí rẹ. bí o bá ní ọmọ, ó ṣe é ṣe kí o ti ṣe àkíyèsí bí wọ́n ṣe jọ ìwọ náà. Díẹ̀ nínú àwọn ohun tí o ti jogún tàbí tí o ti kóran àwọn ọmọ ni ẹ̀kọ́ – àwọn ìwà tí a kọ́ – àwọn díẹ̀ nínú rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀dá – ara ẹ̀jẹ̀-ìran (DNA) rẹ. a ṣe àpéjúwe Dafidi nínú ìwé mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ẹni bí ọkàn Ọlọ́run. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ó jọ Ọlọ́run. Ó ronú, nímọ̀lára, ó sì hùwà ní ọ̀nà tí ó bu ọlá fún Ọlọ́run tí ó sì jọ ìwà tí Ọlọ́run. Ó sì ṣe é ṣe fún wa bákan náà láti ní ẹ̀jẹ̀-ìran (DNA) Dafidi: dídí àwọn ènìyàn tí ó ń pòǹgbẹ Ọlọ́run, tí a ń jọ Ọ́ nípasẹ̀ mímú kí ayé wa bá tirẹ̀ àti ọ̀nà tirẹ̀ mu.

Ebi fún Ọlọ́run túmọ̀ sí ìpọ̀ǹgbẹ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti wíwá ọkàn Ọlọ́run. Dafidi sọ ebi yìí di mímọ̀ nipa sísọ pé òun ń pòǹgbẹ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àgbọ̀nrín ṣe ń mí hẹlẹ sí ipa odò tútù. Bóyá o tin í ìrírí ìgbà irúfẹ̀ ìpòǹgbẹ fún ìwàláàyè Ọlọ́run yìí. Bóyá ní àwọn ìgbà mìíràn, ọkàn rẹ ti pòǹgbẹfún ohun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run. Bóyá o lè gba ebi àkóràn tí kìí rẹ̀ ti Dafidi láti fún ọ ní ìmísí láti gbé ìgbésí-ayé tí ó máa ń gbádùn ìwàláàyè Rẹ̀ aláìlópin. Gbìyànjú láti lo àsìkò pẹ̀lú àwọn tí ó ní irúfẹ̀ ìtara kí o sì kọ́ láti ara ìwà, tàbí ìlànà síse ìpinnu wọn.

Ọ̀rọ̀ Dafidi nínú Orin Dafidi 63 túbọ̀ ṣe àfihàn ìpòǹgbẹ rẹ̀ fún Ọlọ́run àti òye rẹ̀ pé ayé tí kò ní Ọlọ́run ṣófo, kò sì ní èṣo. Orin yìí ṣe àfihàn pé àǹfààní ńlá wíwá Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn jẹ́ àǹfààní níní ìrírí agbára àti ògo Rẹ̀, tí ó ń yí wa padà sí ìrí Rẹ̀. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan tilẹ̀ ti sọ pé a kì í ṣe àwárí Ọlọ́run lójijì, èyí túmọ̀ sí pé a níláti yàn láti mọ̀ọ́mọ̀ wá Ọlọ́run láìsinmi, àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ẹni. Nígbà tí ènìyàn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, a pàdánù ìdàpọ̀-mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́ ọkàn wa le, a sì kọ̀ láti fẹ́ Ọlọ̀run àti àwọn mìíràn. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ eléèérí àti aláìgbọràn, Ọlọ́run fi ìfẹ́ ìràpadà Rẹ̀ lé wa kiri. Ẹ jẹ́ ká mọ̀ọ́mọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní lépa Ọlọ́run pẹ̀lú ìtage-ìfẹ́ ńlá, gẹ́gẹ́ bí ó ti lépa wa pẹ̀lú. A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ Ẹ lékè ohun gbogbo. A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá Á kí á sì lò àwọn àsìkò àkọ́kọ́jí wa pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìdàpọ̀ tòótọ́. Ó jẹ́ ìmọ̀ àyè nipa Rẹ̀ tí ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé E kiri nínú àwọn èrò wa.

Bí o kò bá ti gba Jesu gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà rẹ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. Gbà Á láàyè láti yí ìjìnlẹ̀ ayé rẹ padà pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀. Kí o mọ̀ pé láti wá Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ ni láti ṣe àwárí Rẹ̀. Kí ó sì tún mọ̀ pé láti ṣe àwárí Rẹ̀ ni láti dàbí Rẹ̀ si, àti láti ní ìrírí àwọn ọrọ̀ ògo Rẹ̀.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Ebi

Ìlànà kíkà yìí ṣe àwàjinlẹ̀ bí ebi wa láti mọ Ọlọ́run kí á sì sọ ọ́ di mímọ̀ máa ń gún wa ní kẹ́ṣẹ́ sínú èrèdí rẹ̀ fún ayé wa. Ṣe àwárí ohun tí ó sọ Dafidi di ẹni bí ọkàn Ọlọ́run – àti bí ìwọ pẹ̀lú ṣe lè gbé ayé pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn-kan fún Ọlọ́run, gbígbádùn ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jesu àti gbígbẹ́kẹ̀le láti tẹ́ àìní rẹ larùn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Lawrence Oyor fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://www.youtube.com/lawrenceoyor