Bí a ṣe ń ka bíbélìÀpẹrẹ
Bí a ṣe ń ka Bíbélì: Kín ni Bíbélì?
Báwo ni a ṣe lè ṣe àpéjúwe gidi lórí bí a ṣe lè ka bíbélì, bí a kò bá kọ́kọ́ fi ìdí ohun tí bíbélì jẹ́ múlẹ̀?
Bíbélì jẹ́ Àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ tí Ẹ̀mí Mímọ́ mí sí. Ó jẹ́ ìmọ̀lẹ̀/fìtílà sí ẹsẹ̀ àti ipa ọ̀nà onígbàgbọ́. Ó jẹ́ ìwé ẹ̀mí tí a ti pèsè sílẹ̀ fún gbogbo àìlera ẹ̀mí. Ó jẹ́ ìyè fún àwọn tó rí i àti ìlera sí ara wọn. Èyí túmọ̀ sí pé onígbàgbọ́ jẹ́ afọ́jú àti aláìsàn láìsí ìwé yìí.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpéjúwe wa gẹ́gẹ́ bí amọ̀ lọ́wọ́ amọ̀kòkò, a jẹ́ ọjà lọ́wọ́ Olùpèsè ọjà. Bíbélì ni ìwé-ìtọ́ni ìgbésí-ayé onígbàgbọ́ láti ọwọ́ Olùpèsè gan-an àti ètò ìpìlẹ̀. Nítorí náà, ìwé-ìtọ́ni yìí ṣe àfihàn ìfẹ́ àti ìlànà Ọlọ́run fún ìgbésí-ayé ènìyàn àti àwọn àṣẹ rẹ̀ lórí bí ó ti ẹ kí ènìyàn gbé ayé.
Bíbélì jẹ́ àtìlẹyìn onígbàgbọ́ èyí tí ó ń fún un ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá. Òun ni ìwé òfin tó ń ṣe atọ́nà àwọn ìṣe rẹ̀. Bíbélì ni òfin àtìlẹyìn tí ó ń sọ fún un ní ti àwọn ipò àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú Kristi Jesu nípasẹ̀ àwọn ìlérí rẹ̀. Bíbélì ni Òtítọ́ Náà, ó sì tó tán nínú ara rẹ̀.
Nínú ayé tó ń fi ìgbà gbogbo yí padà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró dájú ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.
Ilé-ayé lè yí padà, Ayé lè kọjá lọ, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní kọjá lọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbélì jẹ́ ìwé pàtàkì nínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ju àkọsílẹ̀ lásán lọ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn onígbàgba máa lo ìgbésí-ayé wọn láyé. Ó tún jẹ́ àkọsílẹ̀ bí àwọn baba ìgbàgbọ́ kan ṣe bá Ọlọ́run rìn nígbà tí wọ́n wà láyé. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti ní òye bí a ṣe ń ka bíbélì.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/