Bí a ṣe ń ka bíbélìÀpẹrẹ
Ìkéde-Ìhìnrere; Ọ̀nà kan láti pín ìròyìn arọ̀ ká.
Lẹ́yìn tí a ti fi ìdí ohun tí bíbélì jẹ́ múlẹ̀ àti ohun tí ó dúró fún nínú ìgbésí-ayé onígbàgbọ́; bí o bá jókòó láti bèèrè ‘Ìdí’ tí o fi ń ka bíbélì, yóò nípa lórí ‘bí’ o ṣe ń ka Bíbélì.
Ṣé kí Bíbélì jẹ́ ìwé ìtàn mìíràn? Ṣé ó jẹ́ àkójọpọ̀ àkọsílẹ̀ ìtàn mìíràn? Ṣé àwọn ènìyàn mímọ́ ẹni Ọlọ́run kàn ní ìmísí Ẹ̀mí Mímọ́ láti kọ Ìwé Mímọ́ ajẹmọ́-ẹ̀sìn mìíràn?
Ó hàn nínú àwọn Ìwé Mímọ́ pé mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ỌLọ́run, bí i idẹ tí a túnṣe ní ìgbà méje. Ó jẹ́ ìlera tí ara àwọn ẹni tí ó wá a rí. A gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ ka Bíbélì. Ìmọ̀ọ́mọ̀ láti ní ‘òye’ àti láti ‘fi ṣíṣe’. Èyí nìkan ni ọ̀nà tí ó lè gbà ṣe onígbàgbọ́ ní àǹfààní.
Bí a bá máa kọ ìdánwò pàtàkì kan tàbí tí a fẹ́ dágbá lé àkànṣe-iṣẹ́ kan, a nílò àwọn àlàyé tó dára. A kò ní kàn fi wàdùwàdù kà á; a máa dù kí ó yé ka kí á sì lo ìmọ̀ tí a ti kó jọ dáadáa. Kínni o lè ronú sí? A máa fojú sọ́nà fún àṣeyọrí nínú ohun náà. Báyìí ni ó gbọ́dọ̀ rí nínú ìgbésí-ayé onígbàgbọ́.
Bí ìyípadà àti ìdàgbàsókè bá jẹ́ òpin ìrìn-àjò bí a ṣe ń ka bíbélì, ó máa jẹ́ déédéé, léraléra àti pé a ó fojú sọ́nà fún àkọsílẹ̀ ìyípadà kan.
Bí o ṣe ń dojú kọ àwọn ìṣòro ayé tí ó nílò ọgbọ́n àtòkèwá tí o sì ń dù láti borí àwọn àrékérekè ọ̀tá, o gbọ́dọ̀ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀ èyi tí ó pẹ̀lú ‘Idà ti Ẹ̀mí’ (Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run).
Rí i dájú pé kíkà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ lájorí ohun àmúṣe lójoojúmọ́ lónìí, àti ni àwọn ọjọ́ mìíràn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbélì jẹ́ ìwé pàtàkì nínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ju àkọsílẹ̀ lásán lọ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn onígbàgba máa lo ìgbésí-ayé wọn láyé. Ó tún jẹ́ àkọsílẹ̀ bí àwọn baba ìgbàgbọ́ kan ṣe bá Ọlọ́run rìn nígbà tí wọ́n wà láyé. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti ní òye bí a ṣe ń ka bíbélì.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/