Bí a ṣe ń ka bíbélìÀpẹrẹ

Bí a ṣe ń ka bíbélì

Ọjọ́ 3 nínú 3

Báwo ni mo ṣe le ka Bíbélì?

Bí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé bá máa fi ojú-ìwé náà sílẹ̀ tí wọ́n sì máa di kíkọ sí wàláà ọkàn ẹni, a gbọ́dọ̀ ní ìbápàdé pẹ̀lú rẹ̀ lójoojúmọ́ àti ní gbogbo ìgbà.

Bí àwọn lẹ́tà inú ìwé náà bá máa pa ni tí ó sì jẹ́ pé Ẹ̀mí níláti fún ni ní ìyè, a jẹ́ pé onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú agbára Ẹ̀mí Mímọ́ láti rìn pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò gbàgbọ́ pé Òun ni ó wà níwájú wọn àti ẹni tí wọ́n pín Ọ̀rọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò yé wọn. Kín ni Jésù ṣe? O ṣí wọn ní iyè kí àwọn Ìwé mímọ́ lè yé wọn. Rí i dájú pé o gbàdúrà kí o tó ka Bíbélì.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ohun-èlò àtúnṣe fún ìbáwí. A gbọ́dọ̀ tọ̀ ọ́ lọ, nítorí náà, pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀. Bí o ṣe ń kà á pẹ̀lú inú-kan, ó ń ṣe àfihàn àwọn àṣìṣe. Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ rẹ ara rẹ sílẹ̀ láti gba ìbáwí náà.

A kò gbọ́dọ̀ kàn ka Bíbélì lásán, a gbọ́dọ̀ tún kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Máṣe kánjú ka àwọn ojú-ìwé rẹ̀. Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa kánjú kúrò ní ọkàn rẹ. O lè ṣe ètò kíkà tó múná dóko kí o sì tẹ̀le lójoojúmọ́.

Jíròrò pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ kíkọ àwọn ìsípayá àti ìmísí tí o rí nínú kíkà á àti kíkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lójoojúmọ́ sílẹ̀. Lọ́nà yìí, yóó dúró sí ọ lọ́nà dáadáa yóó sì tún ṣe é tọ̀ lọ ní àwọn ìgbà mìíràn èyí sì jẹ́ ìrántí tó dára.

Lónìí, kọ Ìwé Míma sí ọkàn rẹ nígbà tí o bá ń kà á.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Bí a ṣe ń ka bíbélì

Bíbélì jẹ́ ìwé pàtàkì nínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ju àkọsílẹ̀ lásán lọ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìmísí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn onígbàgba máa lo ìgbésí-ayé wọn láyé. Ó tún jẹ́ àkọsílẹ̀ bí àwọn baba ìgbàgbọ́ kan ṣe bá Ọlọ́run rìn nígbà tí wọ́n wà láyé. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti ní òye bí a ṣe ń ka bíbélì.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/