Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.Àpẹrẹ
Ìkéde-Ìhìnrere; Ọ̀nà kan láti pín Ìròyìn Ayọ̀.
Ìwé Ìṣe 1:8, ṣe àfihàn pé a nílò láti jẹ́rìí Jésù Kristi, lẹ́yìn tí a bá ti dúrò láti gba agbára. Èyí yọrí sí iṣẹ́ agbára ńlá Pétérù lẹ́yìn ìrírí Yàrá Òkè nínú Ìwé Ìṣe 2. Pétérù, tí a mọ̀ sí ẹni tí ó máa ń ti jú lè ṣe àfihàn ìgboyà ńlá níwájú àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lè ṣe àgbékalẹ̀ tí ó sì lè pín ìròyìn ayọ̀ Jésù pẹ̀lú àwọn èrò tí ó péjọ ní ọjọ́ náà.
Kókó ìkéde-ìhìnrere ní lílè ṣàlàyé ìbí, ikú, àti àjíǹde Jésù Kristi. Bí ó ti jẹ́ pé a bí Jésù, tí ó sì ní láti kú dípò ènìyàn. Ikú rẹ̀ jẹ́ ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa àti pé ó dá wa pàdà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, sí bí ó ṣe wà ní àtètèkọ́ṣe. Pétérù pín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà nínú Ìwé Ìṣe 2, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó sì di ẹni ìgbàlá ní àtàrí èyí.
Ro bí inú rẹ yóò ṣe dùn tó bí o bá jẹ ẹ̀bùn kan, tàbí tí o ṣe àṣeyọrí, inú rẹ yóò dùn si bí o bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́, ẹbí, àti pàápàá ọ̀tá rẹ lè jẹ àǹfààní ńlá yìí. Èyí sì wá yọrí sí sísọ fún wọn, àti gbígbàwọ́n níyànjú láti jẹ́ àjùmọ̀jogún àǹfààní yìí. Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́, ó jẹ́ ojúṣe pàtàkì fún wa láti pín ìròyìn ayọ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ àti àwọn ẹni tí a kò nífẹ̀ẹ́. A ń gbà wọ́n là lọ́wọ́ ewu tó ń bọ̀ sórí ẹnikẹ́ni tí kò gba ìròyìn ayọ̀ yìí.
Ìhìnrere Jésù jẹ́ ìròyìn ìfẹ́. Jẹ́sù fẹ́ wa, nítorí náà ni ó ṣe kú fún wa láti gbà wá là lọ́wọ́ ìjìyà tí ó ń dúró de àwọn ẹni tó kùnà láti gba á gẹ́gẹ́ bí olúwa àti olùgbàlà. A fún wa ní ojúṣe yìí láti pín in pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn tí agbára wá dé. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti gba Jésù Kristi bí Olúwa àti Olùgbàlà, ọ̀kan nínú àwọn ojúṣe rẹ ni láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn. Gbogbo onígbàgbọ́ jẹ Ọlọ́run ní gbèsè iṣẹ́ ìjèrè-ọkàn. Fi pínpín ẹ̀rí rẹ àti kókó ìhìnrere pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí rẹ kọ́ra. Èyí ni ohun tí ìkéde-ìhìnrere jẹ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìbí, ikú àti àjíǹde Jésù mú ìròyìn ayọ̀ náà wá. Ìròyìn ayọ̀ yìí ni ó ti yọrí sí ìgbàlà arayé. Nítorí náà, gbogbo ẹni tí a ti gbàlà ni Jésù Olúwa àti Olùgbàlà ti pa á láṣẹ fún láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìkéde-ìhìnrere, èyí tíí ṣe pínpín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà fún àwọn ẹlòmíràn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/