Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.Àpẹrẹ

Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.

Ọjọ́ 1 nínú 3

Ìkéde-Ìhìnrere; Àṣẹ Ìkẹyìn

Láti Gẹnẹsisi, a lè bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ọ́mọ̀ máa fa ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti ìgbà ìṣubú Adamu àti Eefa nínú Ọgbà Edẹni. Èyí ti jẹ́ ìṣòro àti ìfẹ́ ọkàn Ọlọ́run. A dá ènìyàn fún ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọ̀tá yọ́ wọnú ètò rẹ̀, a sì gba ààyè ènìyàn lọ́wọ́ rẹ̀.

Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run ṣe ọ̀pọ̀ ìgbìyànjú láti dá ìbáṣepọ̀ yìí padà, èyí tí ó yọrí sí ìbí Jésù, ikú rẹ̀, àti lópin ohun gbogbo àjíǹde rẹ̀. Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Jésù pàṣẹ ìkẹyìn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nínú Ìwé Ìṣe 1:7-8. Àṣẹ yìí darí wọn láti jẹ́rìí Jésù Kristi ní onírúurú ibi ní àgbáyé. Ṣùgbọ́n ohun pàtàkì tí ó yẹ láti kíyèsí ni ìnílò láti múra sílẹ̀ kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ ìgboyà ìjẹ́rìí Jésù Kristi kiri yìí. Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti dúró gba Ẹ̀mí Mímọ́ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkéde-ìhìnrere wọn. Ìdí ni pé ìkéde-ìhìnrere nílò agbára.

A lè ka ìkéde-ìhìnrere sí àṣẹ pàtàkì, èyí ní àṣẹ ìkẹyìn Jésù kí ó tó gòkè re ọ̀run. Èyí ṣe àfihàn ìṣepàtàkì iṣẹ́ yìí fún gbogbo onígbàgbọ́. Bí iṣẹ́ yìí bá ṣe pàtàkì, ó rọrùn láti sọ pé ó tún ṣe pàtàkì láti tẹ̀lé àṣẹ àti ìlànà olúwa. Ó ṣe pàtàkì gan-an láti múra sílẹ̀ kí á sì gbàdúrà. Ìdí ni pé Agbára ṣe pàtàkì nínú lílè kéde/wàásù ìhìnrere fún àwọn ènìyàn dáadáa. Èyí máa ń wáyé lẹ́yìn tí onígbàgbọ́ bá ti kún fún ẹ̀mí mímọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ máa ń ran ni lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ìhìnrere fún àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà tó múná dóko. Ọ̀kan nínú àyọrísí kíkún fún Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní Ìwé Ìṣe 2, ni ìgboyà tí ó máa ń wá pẹ̀lú sísọ Ìròyìn Ayọ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ lásán kò lè jíhìnrere, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ tí agbára tì lẹ́yìn.

Láti tẹ̀lé àṣẹ ìkẹyìn yìí, ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀lé ìlànà Jésù Kristi, ẹni tí ó fún wa ní ìlànà yìí, kí á sì tún dúró de Olúwa nínú àddúrà, ọgbọ́n àti ìtọ́ni àtòkèwá láti lè rìn ìrìnàjò ìkéde-ìhìnrere lọ́nà tó múná dóko.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.

Ìbí, ikú àti àjíǹde Jésù mú ìròyìn ayọ̀ náà wá. Ìròyìn ayọ̀ yìí ni ó ti yọrí sí ìgbàlà arayé. Nítorí náà, gbogbo ẹni tí a ti gbàlà ni Jésù Olúwa àti Olùgbàlà ti pa á láṣẹ fún láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìkéde-ìhìnrere, èyí tíí ṣe pínpín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà fún àwọn ẹlòmíràn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/