Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.Àpẹrẹ

Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.

Ọjọ́ 3 nínú 3

Ìkéde-Ìhìnrere; Sísọ di Ọmọ-Ẹ̀yìn.

Iṣẹ́ ìkéde ìhpinrere kò yẹ kó tán sórí pínpín ìròyìn ayọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà. A tún gbà wá ní ìyànjú láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ-ẹ̀yìn kí á sì ran àwọn onígbàgbọ́ titun lọ́wọ́ láti dàgbà nínú ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ ẹni tí Jésù Kristi jẹ́.

Ìwé Ìṣe 8:26-40, a rí ìtàn Fílípì àti ìwẹ̀fà Etopia. Ẹ̀mí Mímọ́ gún un ní kẹ́sẹ́ láti dìde tọ Fílípì lọ láti pín ìhìnrere pẹ̀lú rẹ̀ àti àwọn mọ́lẹ́bí rẹ̀. Ó ṣàlàyé ìwé mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìkókó ti nílò wàrà láti ní okùn bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ní àwọn onígbàgbọ́ titun nílò ìtọ́ni àti ìjánu láti lè gbé ìgbésí-ayé Kristẹni tó dáa. Èyí yóò jẹ́ kí wọ́n jinlẹ̀ kí wọ́n sì rí ìmọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń dàgbà nínú ìgbàgbọ́.

A gbọ́dọ̀ wà ní àìrékọjá fún àwọn ààfààní láti kéde-ìhìnrere nínú ìgbésí-ayé wa lójoojúmọ́, bóyá nípasẹ̀ àwọn ìtàkurọ̀sọ, ìṣe ìjọ́sìn, tàbí pínpín àwọn ohun-èlò fún àwọn ẹni tí ó wà ní àyíká wa. Èyí jẹ́ ọ̀nà láti jogún ọkàn wọn láti tẹ́tí sí ìhìnrere, kí á sì máa kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ọmọ-ẹ̀yìn bí wọ́n ṣe ń dàgbà nínú ìgbàgbọ́. A tún gbọ́dọ̀ sọ ọ́ di ojúṣe wa láti máa gbàdúrà fún àwọn onígbàgbọ́ titun nínú Kristi, pé wọn á jìnlẹ̀ wọn kò sì ní ṣe é ṣí nídìí, kí wọn má ba à lè gbá wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀kọ́ oríṣiríṣi.

Ní ojoojúmọ́, lo àsìkò nínú èrò àti àdúrà, bí o ti ń dù láti dàgbà ninú òye rẹ sí ìkéde-ìhìnrere àti gbígbẹ́kẹ̀lé Ẹ̀mí Mímọ́. Rántí pé ìkéde-ìhìnrere jẹ́ pínpín ìfẹ́ àti òtítọ́ Jésù Kristi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, bí a ṣe ń gba Ọlọ́run gbọ́ pé yóò ṣiṣẹ́ ní ọkàn wọn láti mú àyípadà wá.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ìkéde-Ìhìnrere; Ìfẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo onígbàgbọ́.

Ìbí, ikú àti àjíǹde Jésù mú ìròyìn ayọ̀ náà wá. Ìròyìn ayọ̀ yìí ni ó ti yọrí sí ìgbàlà arayé. Nítorí náà, gbogbo ẹni tí a ti gbàlà ni Jésù Olúwa àti Olùgbàlà ti pa á láṣẹ fún láti dìde fún ìgbàlà àwọn ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìkéde-ìhìnrere, èyí tíí ṣe pínpín ìròyìn ayọ̀ yìí kan náà fún àwọn ẹlòmíràn tí kò tíì di ẹni ìgbàlà.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/