Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ
Ìséra-ẹni láti lè Bẹ̀rẹ̀
Ayaà mi Amy, àwọn ọmọ mi, àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ fúnmi ma fi yé ọ wípé kìíṣe pé mo kàn fẹ́ràn láti máa kọ́ àwọn adarí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ǹkan tó nípa nínú ìṣẹ̀dá mi. Mo gbàgbọ́ wípé nígbà tí adarí bá ń gbèrú síi, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú yóò tẹ̀síwájú.
Ìbéèrè kan nìyí fúnwa láti gbàrò: “Ṣé dídarí àwọn ènìyàn kàn jẹ́ ǹkan tó wù mí láti ṣe ni, àbí ara ìṣẹ̀dá mi lójẹ́”?
Ìdáhùn rẹ ṣe pàtàkì nítorí kìkìdá ètò ìdàgbàsókè ọ̀pọ̀ àwọn adarí ni àfojúsùn ohun tí yóò ṣe: “Mofẹ́ gbìyànjú síi pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, mo máa ṣe àwọn ǹkan ìwúrí fún aya mi, mo máa ṣe àwọn ǹkan tí yóò ró àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi lágbára síi.” Àmọ́, àwọn adarí tó lókìkí jùlọ máa ń ṣe àfojúsùn àtúnṣe èèyàn: “Mo máa jẹ́ ìyá onísùúrù tí ń fẹ́ràn tọkàntọkàn, Mo máa jẹ́ ọkọ tí ń ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ tí sì ń fẹ́ràn rẹ̀ dáradára, Mo máa jẹ́ olùṣàkóso tí ń darí pẹ̀lú àpẹẹrẹ.”
Àwọn adarí tó lókìkí jùlọ máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àtúnṣe èèyàn tí wọn yóò sì jẹ́kí ṣíṣe wá lẹ́yìn èyí.
Tí a bá máa fi gbèdéke àwọn aláìgbàgbọ́ wòó, Jésù ló fẹ́rẹ̀ jẹ́ adarí olókìkí jùlọ tó la ayé yìí kọjá. Ọdún mẹ́ta péré ni Ó fi ṣiṣẹ́ ní gbangba tó sì ní ẹgbẹ̀rún-mẹ́wàá-ólé ọmọ lẹ́yìn. Okòó ọdún lẹ́yìn èyí, àwọn ìwé gbajúgbajà ló ń sọ ìtàn ayéè Rẹ̀, àti wípé egbàágbèje ènìyàn ni gbogbo àgbáyé ló ti jọ̀wọ́ ìgbésí ayé wọn láti máa tẹ̀lée.
Ní ìgbà méje nínú ìwé Jòhánù, Jésù ṣe ìkéde àwọn ọ̀rọ̀ àtúnṣe èèyàn tó lágbára. Bí o ti ń ka àwọn ọ̀rọ̀ náà lónìí, wàá ṣe àkíyèsí wípé gbólóhùn Rẹ̀ kààǹkan lóní ipá lórí iṣẹ́ Rẹ̀ àti wípé ipá yìí sì wà títí dòní.
Nígbàtí o bá mọ ẹni tí ìwọ íṣe, o máa mọ ohun tó kàn láti ṣe. Ní pàtàkì jùlọ, o lè bi araà rẹ, “kíni ẹni tí ó wù mí láti jọ yóò, ṣe?” Ohunkóhun tí o bá pinu láti ṣe, mo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn láti bẹ̀rẹ̀ díẹ̀ díẹ̀. Ìséra-ẹni díẹ̀ díẹ̀ tí a ṣe lóòrè kóòrè ni yóò mú èsì dídára wá lẹ́yìnwá ọ̀la.
Tí obá fẹ́ jẹ́ olùdarí tí ń káàánú, o lè máa fi ìwé ìwúrí, ó kéré jù, ẹyọkan ránṣẹ́ lójojúmọ́. Tí o báfẹ́ jẹ́ ènìyàn tó létò, o lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe ìtọ́jú ibùsùn rẹ. Tí o bá fẹ́ jẹ́ olùdarí tí ń tẹ̀lé ọkàn Ọlọ́run, bóyá o nílò láti máa bá A sọ̀rọ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ kàǹkàn. Ṣe ohun tí yóò mú ọ di ẹni tí o fẹ́ dà gẹ́gẹ́bí olùdarí.
Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀: Ọlọ́run, Ìwọ lo dámi; O sì mọ̀mí. Ǹjẹ́ Ìwọ yóò fúnmi ní ọ̀rọ̀ tí yóò mú mi mọ ẹni tí mojẹ́ àti ipá láti mọ ìgbésẹ̀ tí mo ní láti gbé?
Gbé àwọn ọ̀rọ̀-àkáálẹ̀ mi nípa ìdarí yẹ̀wò láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi .
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.
More