Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ

Six Steps To Your Best Leadership

Ọjọ́ 2 nínú 7

Ìgboyà láti Kó Ara Ẹni ní Ìjánu

Tóbá ní ẹnìkan tí a bí pẹ̀lú ẹ̀bùn àmútọ̀runwá, fún ìdarí tí kò láfiwé, Sámúsìnì lẹni náà, síbẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ di rúdurùdu nítorí kò ní ìgboyà láti kó ara rẹ̀ ní ìjánu.

Àkàràa rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹnu bepo nínú ìwé Àwọn Adájọ́ 16:1 NIV: Lọ́jọ́ kan Sámúsìnì lọ sí Gásà, níbi tó gbé rí obìnrin aṣẹ́wó kan.

Gásà jìnà sì ìlú Sámúsìnì, Sórà, níwọ̀n ibùsọ̀ márùn-dín-lọ́gbọ̀n. Gásà jẹ́ olú-ìlú àwọn Filísínì níbi tí Sámúsìnì tí jẹ́ ọ̀tá wọn tí ó gbajúmọ̀ jùlọ. Láfikún, nígbà ayéè Sámúsìnì—kò sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kankan. Sámúsìnì máa ń rìn fún máhílì márùn-dín-lọ́gbọ̀n láti lọ rí aṣẹ́wó. 

Èyí jásí ìṣísẹ̀ nígbàa 56,250. Ayéè Sámúsìnì kò kàn ṣàdédé bàjẹ́ lójijì. Ní ṣẹ lógbé ìṣísẹ̀ 56,250 ni ipa àìtọ́. 

Èyí kò yàtọ̀ fún àwọn ẹgbẹ́ wa, àwọn ilé-iṣẹ́ wa, iṣẹ́-ààyò wa, àlàáfíà, àti ẹbíi wa. Kò sí ẹni náà tó máa pinu láti wó ayé ara rẹ̀ palẹ̀ lójijì. Lọ́pọ̀ ìgbà èyí máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu búburú kan, ìṣísẹ̀ àìtọ́ kan, ìwà burúkú kan, ní ọjọ́ kan. 

Kí ni a wá nílò? Ìgboyà láti kóra wa ní ìjánu. Láti ṣọpé rárá. Láti tẹ̀ẹ́ jẹ́jẹ́. Láti tako gbígbé ìṣísẹ̀ mìíràn ní ipa àìtọ́. Kíni o nílò láti kó ara rẹ̀ níjàánu lé lórí? 

Èyí kọjá kíkọ ǹkan tí gbogbo ayé mọ̀ ní àìda ṣílẹ̀. Ṣé olùṣàkóso ni ìwọ íṣe? Bóyá ó ní ìpàdé kan tí kò ní ìtumọ̀ tí o nílò láti fòpin sí. Tí o bá ń sapá lóríi iṣẹ́ tí kò ní ìtumọ̀, o kò lè rí àbájáde tó ń mú ìwúrí wá ní ìdí rẹ̀. Kíni àwọn iṣẹ́ to nílò láti fòpin sí? Kíni àwọn iṣẹ́ pàtàkì tí o nílò láti fòpin sí kí o ba lè gbèrú gẹ́gẹ́bí adarí? Láti gbé ǹkan tó tóbi ṣe gẹ́gẹ́bí adarí, óṣeéṣe fún ọ láti dín àwọn ǹkankan kù. 

Bóyá tìrẹ kìíṣe nípa iṣẹ́. Bóyá bíi Sámúsìnì ni ìwọ ṣe rí, tí o sì ti gbé ìṣísẹ̀ kan, méjì, tàbí okòó ní ọ̀nà àìtọ́ nípa ìbárẹ́, ìhùwàsí, tàbí àlàáfíà rẹ. Èyí yóò wúlò pẹ̀lú—kò tíì pẹ́ jù fún ìgboyà láti fòpin síi. 

Gba èyí rò: Pẹ̀lú àfojúsùn ohun tí mò ń lépa, kíni ǹkan náà tí mo nílò ìgboyà láti fòpin sí? Kíni àwọn ìṣísẹ̀ tí máa ń mú àbájáde tí kò dára wá? Kíni àwọn ìhùwàsí tàbí àwọn ààyè tí máa ń kó mi sí wàhálà? Ta ni olè ràn mí lọ́wọ́ láti fòpin síi?

Fi Bukumaaki wa pamọ́ nípa bí a tií bẹ̀rẹ̀ tàbí fòpin sí ìhùwàsí .

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Six Steps To Your Best Leadership

Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/