Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ

Six Steps To Your Best Leadership

Ọjọ́ 3 nínú 7

Ẹni tí A lè ró Lágbára

Ọkàn lára àwọn ǹkan tí Jésù kọ́kọ́ ṣe nínú ọdún mẹ́ta tó fi ṣiṣẹ́ ní gbangba ni láti ṣe àwárí àwọn ènìyàn tólè ró lágbára. Ó rí àwọn méjìlá, ṣùgbọ́n ìwọ kìíṣe Jésù, bóyá ẹyọ kan ni yóò pé fún ọ láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú?

Tí o kò bá ró àwọn mìíràn lágbára, ohun kan tó dájú ni pé—wàá kan di ìdíwọ́ fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ rẹ ni. Àṣeyọrí iṣẹ́ rẹ kọjá ìsáré sókè-sódò lásán; àṣeyọrí iṣẹ́ rẹ nííṣe pẹ̀lú àwọn tí o ró lágbára.

Tí Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, bá nílò àwọn ènìyàn láti gbé iṣẹ́ ṣe, kò lè rọrùn fúnwa láti dá iṣẹ́ tóní ìtumọ̀ kankan ṣe. Kọ́ àwọn ènìyàn kí ẹ sì wá fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣe ohun ńlá. 

Lánọ̀ọ́ a sọ̀rọ̀ nípa níní ìgboyà láti kóra wa níjàánu. O tilẹ̀ lè nílò láti fòpin sí àwọn ǹkan tí o fẹ́ràn. To bá ní ìwé-ìjábọ̀, iṣẹ́, tàbí ètò kan láti ṣe, O bá gba gbígbé iṣẹ́ náà fún ẹlòmíràn rò. Bí o bá ní èèyàn tó lè ṣe ìdákan-nínú-méjì iṣẹ́ tofẹ́ ṣe tí wọ́n sì ní ìfiyèsí láti gbèrú si, gbé iṣẹ́ náà fún wọn kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbèrú nínú rẹ̀. 

Ìgbésẹ̀ ńlá àkọ́kọ́ fún Jésù ni láti wá àwọn ènìyàn tí ó lè ró lágbára, ìgbésẹ̀ Rẹ̀ ìkẹyìn lórílẹ̀ ayé sì ni láti gbé àwọn iṣẹ́ Rẹ̀ tó ṣe pàtàkì lé àwọn ọmọlẹ́yìn lọ́wọ́. Èyí tí a sábà ma ńpè ni Àṣẹ Ńlá, tí a bá sì wòó dáradára, ìgbésẹ̀ tó ṣe àǹfààní ní.

Kíni o lè fi fún-ni? Tani o lè fi fún? Báwo lo ṣe fẹ́ kọ́wọn tí wọn yóò fi dàgbà sókè?

Nígbàtí o bá ró àwọn tó yẹ lágbára, wọ́n máa ní ìwúrí, wọ́n máa gbèrú ní ipa ìdarí, ìwọ lè wá fi àfojúsùn sí ǹkan mìíràn, ètò ìdarí rẹ yóò sì wá ní pọn síi. 

O lè ní ìṣàkóso lóríi iṣẹ́ rẹ, tàbí o lè gbèrú síi, ṣùgbọ́n o kò lè ní méjèèjì papọ̀. Tani ìwọ yóò ró lágbára?

Bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀: Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé O jẹ́rìí mi láti darí àwọn ènìyàn Rẹ wọ̀nyí. Tani mó nílò láti ró lágbára? Nípa kíni mo nílò láti ró wọn lágbára?

Yẹ ipele 16 àti 17 nínú ọ̀rọ̀-àkáálẹ̀ mi wò láti kọ́ síi.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Six Steps To Your Best Leadership

Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Craig Groeschel àti Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fun àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.craiggroeschel.com/