Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jùÀpẹrẹ
Ètò tí O lè Ṣẹ̀dá
Mofẹ́ kí o ronú nípa ìṣòro kan ní ibisẹ́, nínú ẹgbẹ́, nínú ilé, tàbí nínú ayéè rẹ tó máa ń jẹ yọ ní ìgbà-dé-ìgbà. O lè ni lérò wípé ìṣòro ìṣàkóso àmì-ẹ̀yẹ, ìtọ́jú oníbàárà, tàbí ti ilé tó dàrú ló jẹ́, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ìṣòro àìlétò ní máa ń fà á.
Gẹ́gẹ́bí adarí, ó máa ń rọrùn fúnwa láti fẹ̀sùn kan àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ wa fún àwọn ìdojúkọ nígbà tí àìsí ètò láti ọ̀dọ̀ wa ló jẹ́ olórí ìṣòro.
O tún lè máa rò ó wípé, “a kò ní ètò kan pàtó,” tàbí “bí iṣẹ́ ti ń wá ni a tií ṣeé: a kò nílò ìṣàkóso nípa ètò.” Ṣùgbọ́n, kò sí ẹnìkan tí kò ní ètò. Ètò tìrẹ lè jẹ́ ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn íméelì ní òwúrọ̀, yíyanjú ìṣòro bí wọ́n ti ń yọjú sí ọ, kí o sì wá darí sílé lẹ́yìn tó ti rẹ̀ ọ́ teyín-teyín. Ètò kan náà nìyẹn.
Àwọn ètò wà tí a gbé kalẹ̀ tàbí tó kàn ṣúyọ fúnra rẹ̀, ọ̀nà-kọnà tí kò báà jẹ́, ètò kò ṣeé gbá ṣẹ̀gbẹ́. Ètò tí ò ń tẹ̀lé lè wáyé nítorí o ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ tàbí nítorí o gbà á láàyè. Nítorí náà, tí o bá fẹ́ àbájáde tó dára ju àtẹ̀yìnwá lọ, bẹ̀rẹ̀ ètò tó dára ju èyí tó wà tẹ́lẹ̀.
Nínú oríi Bíbélì tí ó ṣáájú, ayé wà ní júujùu, Ọlọ́run sì pàṣẹ pé, “kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà.” Ó sì wá tẹ̀síwájú láti ya ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn sọ́tọ̀, ayé àti ọ̀run sọ́tọ̀, ilẹ̀ àti omi sọ́tọ̀, ẹyẹ àti ẹja sọ́tọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí o ṣe àkíyèsí wípé Ọlọ́run máa ń yanjú àwọn ètò kan papọ̀ kí ó tó tẹ̀síwájú. Lákòótán, Ọlọ́run dá ènìyàn ó sì fún wọn ní ìtọ́ni nípa ìtọ́jú ohun gbogbo—pẹ̀lú àfikún ètò ìsinmi ẹ̀kan l'ọ́sẹ̀.
A bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá pẹ̀lú ètò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Ìjọ náà ní ara kan pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà tó ní iṣẹ́ kan pàtó tí wọ́n ńṣe. Ètò nìyẹn. Ètò tó ní adarí tí ó yanjú—èyí tí í ṣe Jésù.
Bó ti rí nínú ayé, nínú Ìjọ, nínú araà rẹ, kìkìdá ètò ni ìgbésí ayé rẹ jẹ́. A kìí ṣe kòńgẹ́ ètò dídára. Ní ṣeni a máa ń dìídì ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀.
Àgbékalẹ̀ ètò wo lo nílò láti ṣe fún èsì tí o fẹ́?
Gba èyí rò: Ǹjẹ́ mo ti fi Jésù ṣe adarí pònkárí ètò mi—èyí tí í ṣe ayé mi? Àwọn rúkè-rúdò wo ni mò ń kojú, àti wípé irú ètò wo ni yóò mú mi borí wọn?
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.
More