Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ

Break Free From Envy a Six-Day Reading Plan by Anna Light

Ọjọ́ 1 nínú 6

Ọjọ́ 1 Ìlara jẹ́ Apanirun 

Nínú gbogbo àwọn ìtara tí mo rò pé mo ní, ìlara kò sí láàrin atọ́kò mi. Owú? Bẹ́ẹ̀ni. Àfiwéra? Ahh, l'ójoojúmọ́. Ìbànújẹ́? Ìbínú? Àníyàn? Ìkórira pàápàá? Ṣùgbọ́n nígbàtí mo gbọ́ ẹ̀kọ́ kan l'órí ọ̀rọ̀ yìí láti inú adarọ-esẹ̀ kan tí mo fẹ́ràn, mo mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wípé gbogbo àwọn ìtara yòókù yìí fìdímúlẹ̀ nínú ẹ̀mí ìlara.

Mo kórira níní àwọn ìmọ̀lára òdì. L'órí ìdánwò ènìyàn tí a pè ní Enneagram, mo jẹ́ irú “7”. Gẹ́gẹ́ bíi “7”, tí mo bá lè yàgò fún ìrora tí àwọn ẹ̀dùn òdì, mo máa wá ọ̀nà láti ṣe é. Láti díbọ́n pé wọn kò já mọ́ ǹkankan kò ge fún mi. Mo fẹ́ dé gbòǹgbò ìmọ̀lára mi kí n lè l'ómìnira ní tòótọ́, kì í ṣe láti díbọ́n pé mo ní òmìnira. Ó gba iṣẹ́, kíkọ́ láti mú àwọn ìmọ̀lára òdì wọ̀nyẹn wá sí ìmọ́lẹ̀ àti sí Ọlọ́run fún wọn láti pàdánù agbára wọn, ṣùgbọ́n iṣẹ́ náà tó bẹ́ẹ̀. Mo mọ̀ pé ìdí nìyí tí mo fi ń yára láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí òmìnira ọpọlọ, ti ìmọ̀lára, àti ti ẹ̀mí—nítorí pé mo ti tiraka jinlẹ̀ pẹ̀lú òkùnkùn tí ó ń wá láti inú gbígbé ní ìgbèkùn sí àwọn ìmọ̀lára òdì wọ̀nyẹn.

Ìjàkadì yẹn ti di dandan sí wíwá òmìnira òtítọ́ àti pípẹ́ fún ara mi. Ó jẹ́ ìrírí tí mo fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní, bí mo sì ṣe ń rí àwọn ìpele òmìnira tuntun, mo mọ̀ pé n kò lè pa wọ́n mọ́./p>

Ètò kíkà tí ó tẹ̀lé yìí jẹ́ ìrìn-àjò mi láti ṣ'àwárí òmìnira láti ìlara àti ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó wà láti òmìnira yẹn.

Kíni ìlara? Kí ló dé tí ó ṣe ṣe pàtàkì fún wa láti ní òye bí ó ṣe kàn wá ní òní? Ayé tí à ngbé ní ààyè ìbísí fún ẹ̀mí ìlara. Ní báyìí, ju ti ìgbàkigbà rí lọ, a dojú kọ ìgbésí ayé gbogbo èèyàn bí wọ́n ṣe fẹ́ kí wọ́n rí i—bí wọ́n ṣe ń darí é—ìfiwéra pẹ̀lú ìgbésí ayé tiwa fúnra wa lè ru ìlara sókè nínú wa. A ń gbé nínú àṣà ìlara, a sì lè má tilẹ̀ mọ bí ẹ̀mí yìí ṣe ń ṣe ipalára fún ìlera ọpọlọ, ìmọ̀lára, àti ti ẹ̀mí wa.

A lè ṣ'àpèjúwe ìlara bíi ìmọ̀lára àìní ìtẹ́lọ́rùn tàbí ìfẹ́ ibi ti ohun-ìní, àwọn ìdáyàtọ̀, tàbí oríire ẹlòmíràn. Ó jẹ́ gbòngbò àwọn ẹ̀dùn òdì wọ̀nyẹn bíi owú àti àfiwé, ṣùgbọ́n ìlara lọ jinlẹ̀ jù wọ́n lọ. Owú sọ pé “Ìbá ṣe pé mo ní ohun tí wọ́n ní.” Ìlara sọ pé, “Kí ló dé tí wọ́n fi ní ohun tí n kò ní?” Ìlara kórira láti rí àwọn ènìyàn míràn ní ìdùnnú yíò sì yọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ nígbàtí àwọn ẹlòmíràn bá ṣubú. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Dorothy Sayers ti sọ, ìlara ni “láti fi àrankàn wo ẹlòmíràn.” Apanirun ni, ìpele nlá; kò lè gbà kí a fi ìfẹ́, ọ̀wọ̀ tàbí ìm'oore hàn

“Ìlara á máa je egungun” ni òǹkọ̀wé Òwe sọ. Ó jẹ́ májèlé sí ọkàn. Ẹran ara wa yóò nígbà gbogbo n'ìmọ̀lára oró ìlara nígbà tí a bá fún ní ànfààní. Ó gba iṣẹ́ àròjinlẹ̀ nínú ẹ̀mí wa láti borí ìdanwò láti ṣe ìlara, àti láti ní òmìnira láti yọ̀ ní tòótọ́ pẹ̀lú àṣeyọrí àti ojú rere àwọn ẹlòmíràn.

Ìbàjẹ́ ìlara n ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà méjì. Dájúdájú, ẹ̀yin kò fẹ́ kí ẹ̀mí ìlara yìí máa gbé nínú ọkàn yín, ṣùgbọ́n kí ni ìpalára tí ìlara ń fà nígbà tí ó bá wa láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn? Mo ti wà ní ìdá méjèèjì, bí o bá sì ṣe ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò yìí, o lè rí bí ìlara ti ṣe ba ọkàn rẹ jẹ́ àti pàápàá ìbátan rẹ pẹlú àwọn míràn. Àwọn àfiwé méjèèjì pè fún wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ ti ẹ̀mí nínú ọkàn àti ìmọ̀ wa láti ní òmìnira.

Ìrètí mi ni pé ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀ nínú ètò yìí, ìwọ yóò ní ìmọ̀, àwọn irinṣẹ́, ìwé-mímọ́, àti ìgboyà tí o nílò láti tú ara rẹ s'ílẹ̀ kúrò nínú ìlara.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Break Free From Envy a Six-Day Reading Plan by Anna Light

Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Anna Light (LiveLaughLight) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ lọ sí: http://www.livelaughlight.com