Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna LightÀpẹrẹ
Day 5—Gbòǹgbò Owú Naa
Ní ọjọ́ kan, èmi àti ọmọbìnrin mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà rìnrìn afẹ́ lọ sí aginjù kékeré kan ládùúgbò wá. Inú wa dùn wípé òtútù yìnyín ti lọ, èyí ló mú wa ṣeré lọ sí inú aginjù tó wà ní ìtòsí ilé. Lẹ́yìn èyí, ni ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ nípa bí òhun ti fẹ́ràn ìṣẹ̀dá koríko àti ẹranko inú pápá tó. Ìgbà míràn ó máa sọ wípé “mo fẹ́ràn láti máa ṣeré níta,” ní ìmọ̀ wípé gbogbo rẹ̀ yóò padà rùn síi nígbà tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ̀ ní ìlú Oklahoma. “Ọmọbìnrin tó fẹ́ràn ìṣẹ̀dá ni mí, èmi nìkan sì ni!” Gbólóhùn yí yà mí lẹ́nu. Ǹkan tó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi níbẹ̀ ni wípé ọmọ kékeré ọdún mẹ́fà kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dàbí òhun, tàbí ṣe ǹkankan tó jọmọ́ tiẹ̀. Mo wá sọ fún un wípé “ìṣẹ̀dá wà ní jàntírẹrẹ fún gbogbo ènìyàn láti jẹ̀gbádùn.”
Tí a kò bá ní tanra wa jẹ, gbogbo wa la ní irúfẹ́ ìwà yí lọ́wọ́. A fẹ́ jẹ́ ènìyàn àrà-ọ̀tọ̀—láti dá yàtọ̀—ó sì ṣeé ṣe kí ara wa má gbàá tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa iná ìtumọ̀ yí. Bí mo ti ń ro ǹkan wọ̀nyí ni mo ti ri wípé ìdíyelé ara ẹni ní ń fa èyí.
Ó lè ṣòro púpọ̀ fún ọkàn wa tó ti ní òdiwọ̀n láti ní òye nípa ọ̀pọ̀ ǹkan tí a ti ṣètò fún wa nínú Kristi. A ní ìfòyà wípé “ìbùkún” tàbí oríire náà ma tán, tàbí wípé bóyá Ọlọ́run máa gbàgbé wa. A fẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wa, kí wọ́n dá wa mọ̀, kí wọ́n sì gbóríyìn fún wa. Àmọ́ nígbà tí a bá rí ẹlòmíràn tó ń di alábùkúnfún ó ma ń sọ owú jí nínú wa tó bẹ́ẹ̀ tí a máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iyèméjì bóyá Ọlọ́run fẹ́ wa rárá.
Owú ò jẹyọ tààrà látinú ìkórìíra fún oríire àwọn ẹlòmíràn. Èso owú lásán nìyẹn. Mo ní ìdánilójú wípé àìní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ni gbòǹgbò owú.
Owú kò jìnà sí sàkání ìrírí ìjákulẹ̀ tàbí ìbínú sí Ọlọ́run. Kìíṣe pé mo banújẹ́ nítorí àwọn kàn ní ǹkan tí n kò ní. Ìbànújẹ́ náà ṣú yọ nítorí Ọlọ́run kò tíì tàbí kò ní fún mi ní ǹkan tí mo ní ìgbàgbọ́ pé ó tọ́ sí mi, tí mo bá sì ma sọ òtítọ́, n kò gbàgbọ́ wípé Ó mọ ohun tó ńṣe.
Ṣèbí Ọlọ́run dáadáa la pè É? Àìní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run a máa ṣú yọ látinú àìní ìmọ̀ pípé nípa irúfẹ́ ẹ̀dá tí Ọlọ́run jẹ́; pẹ̀lú àìní ìmọ̀ tàbí ìrántí ìhùwàsí Rẹ̀ gan-an. Àwọn ọ̀nà tó fi dára kò ní òdiwọ̀n. Ó ṣèlérí láti mú ohun gbogbo ṣiṣẹ́ sí rere fún wa, àmọ́ a kò lè ṣe ìdiwọ̀n bó ti dára sí pẹ̀lú bó ti ṣe mú ìfẹ́ ọkàn wa ṣẹ sí. Èyí kìí ṣe ọ̀nà tó m'ọ́gbọ́n dání láti tọ́ ọmọ. Kódà, ó ṣe pàtàkì fún wa láti rántí wípé Òun ni ìfẹ́, fún ìdí èyí a lè gbé gbogbo ǹkan tó bá ṣe sórí gbèdéke yìí.
Ó tún pọ̀ jọjọ, ju bí a ti nílò lọ. Orin Dáfídì sọ wípé Òun “ló ni màálù tó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún òkè,” èyí tó túmọ̀ sí wípé Ó ba lórí ohun gbogbo àti wípé kò ní díbàjẹ́ láéláé. Ǹjẹ́ a tilẹ̀ gba èyí gbọ́? Ǹjẹ́ a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wípé òhun ni arínúróde, olùmọ̀ran ọkàn àti wípé ó ṣeé ṣe fún wa láti má ní òye nípa àwọn ǹkan? Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ ṣeé ṣe wípé àwọn ǹkan tó ṣètò fún wa ju bí ojú inú wa ti lè rí lọ? Ṣé a ní ìgbàgbọ́ nínú èyí? Mo ti gbọ rí tí àwọn èèyàn sọ wípé, “Nínú ko ní Ọlọ́run, tàbí kó ní òye, àmọ́ kò wọ́pọ̀ fún ènìyàn láti ní méjèèjì.”
Ṣé Ọlọ́run tó fún wa?
Kí a tó lè dé ibi ìsinmi níbi tí Ọlọ́run ti jẹ́ tító wa, a ní láti mọ̀ ọ́ dáradára. A lè ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run nígbà tí a bá wá sí iwájú Rẹ̀ lóòrè kóòrè, láti mọ̀ Ọ́ si. Bí Brennan Manning ti má ń sọ, “Bí o bá ṣe fẹ́ràn Ọlọ́run sí ni o maṣe gbẹ́kẹ̀le sí. Àti pé ìwọ yóò nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n tí Ó fi ọwọ́ kàn ẹ́, dípò pé ìwọ ti fi ọwọ́ kàn ọ́.”
Níbẹ̀ lati mọ̀ wípé kò ka ẹ̀ṣẹ̀ fún wa tàbí ní ìpinnu láti jẹ wá níyà. Baba tó dára púpọ̀ ni, ó sì ṣetán láti bùkún àwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́ ó lè yàtọ̀ sí ǹkan tí àwa ń retí. Tí a bá lè gba owú, iyèméjì, ìbínú, àti ìbànújẹ́ láàyè láti tì wá lọ sí oókan àyà Ọlọ́run dípò títì wá kúrò níbẹ̀, a máa padà ri wípé Ó ní ètò tó tóbi ju èrò ọkàn wa lọ. Ìrètí wa kìíṣe nípa rírí ǹkan tí a fẹ́ gbà. Ìrètí wa dá lórí títi ara wa lọ sí oókan àyà Rẹ̀, ibi tí a ti máa rí ìmúṣẹ pípé.
Nípa Ìpèsè yìí
Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.
More