Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ
Ohun kan ṣoṣo tí a fẹ́ ni ìfẹ́ òtítọ́.
Tí ó bá jẹ́ pé ìfẹ́ kan ṣoṣo tí a ní ni láti nífẹ̀ẹ́ Kristi ní kíkún, a gbọ́dọ̀ fà mọ́ ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀, kí a sì tẹ̀lé E ní kíkún. Láti tẹ̀lé E ní kíkún, a gbọ́dọ̀ gbé àgbélèbú wa kí a sì sọ ẹ̀mí wa nù láti gbé ti Rẹ̀. A gbọ́dọ̀ kú sí ara wa, sí àwọn ọ̀nà wa, àwọn ìfẹ́ wa, ìgbéga wa. Nínú ikú yìí - ikú ìfẹ́-ara-ẹni - ni ìfẹ́ Kristi fi máa wà láàyè nínú wa. A gbọ́dọ̀ wò Ó - kìí ṣe ẹlòmíràn, tàbí ǹkan míràn - fún àlàáfíà, ìtẹ́wọ́gbà, ìtọ́sọ́nà, àti ìyè. A gbọ́dọ̀ wá gbogbo ayọ̀ wa nínú Rẹ̀. Òun gbọ́dọ̀ jẹ́ èrè nlá wa. A gbọ́dọ̀ sinmi ní kíkún lórí ànfàní tí a n retí nínú Rẹ̀. A gbọ́dọ̀ sinmi nínú Olúwa, kìí ṣe nínú òdodo tiwa. A kò gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀lẹ́ ara wa. Ní tòótọ, tí a bá fi ara wa sílẹ̀ sí ẹ̀yìn ni a yóò pàdé Kristi ní kíkún.
Àmọ́ ìfi ara ẹni sílẹ̀ kìí ṣe iṣẹ́ kékeré. Ó túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀nà ti ara wa sílẹ̀, àwọn òye, ìfẹ́, àwọn ìbẹ̀rù, àwọn àìláàbò, àwọn ìṣòro, àwọn ìfiyèsí, àwọn ohun-ìní, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí a bá se n fi àwọn ìtùnú àti àwọn ọ̀nà ti ayé yìí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a óò lè fara mọ́ àwọn ìtùnú àti àwọn ọ̀nà ti Kristi pẹ́kí pẹ́kí. Bí a bá ṣe ń yọ̀ nínú Kristi tó, bẹ́ẹ̀ ni a ó fẹ́ láti máa lè sìn ín àti kí a jìyà fún Un síi, ewu láti fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì dínkù. Ayọ̀ Olúwa l‘agbára wa.
Bí a bá ń wá láti kún fún Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀, a gbọ́dọ̀ rìn pẹ̀lú ọkàn wa ní ìṣọ̀kan sí tiRẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, bí ó ti wù kí ìjì náà le tó tàbí bí ìdààmú ti pọ̀ tó tàbí bí ìdánwò tí ó ń bọ̀ lọnà wá ti lágbára tó.
Ní ọ̀la, a yóò ríi ohun ti èyí jẹ́ ní ojú ayé ojoojúmọ́.
Fífi Òtítọ́ pamọ́ sínú Ọkàn: Yan ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ kan láti gbé sí ọkàn láti tún ọkàn rẹ ṣe àti yí ọkàn rẹ padà.
Pípa Ara: Ẹsẹ̀ wo pàtó ni ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ ti o kọ n kojú nínú ìgbésí ayé rẹ? Pọ́ọ̀lù sọ fún wa ní pàtàkì pé kí a bọ́ ara ògbólógbòó sílẹ̀.
Mímú Òtítọ́ wá sí ààyè: Gbé ara titun wọ̀ - Kristi. Àwọn àtúnṣe wo pàtó ni o nílò láti ṣe nínú ìrònú tàbí ìwà tàbí ìhùwàsí rẹ láti tẹrí ba fún Un àti láti fi òtítọ́ Rẹ̀ sí ọkàn àti àyà rẹ?
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ yìí làti Ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend ṣe àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ ìfẹ́ ní ìlànà Bíbélì àti bí a ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
More